Hadith for the World
Tap the image to view it full size
Fik'hu ati ìpìlẹ̀ rẹ

Lati ọdọ ọmọ Abbās - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji - lati ọdọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o sọ pe:

Available in 62 languages
«Lati ọdọ ọmọ Abbās - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji - lati ọdọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o sọ pe: «Wọn pa mi laṣẹ ki n fi ori kan'lẹ lori oríkèé meje: Lori iwaju ori, o si na ọwọ rẹ si imu rẹ, ati ọwọ mejeeji, ati orunkun mejeeji, ati awọn ọmọ ika ẹsẹ mejeeji, ati pe ki a ma ka awọn aṣọ ati irun».»

Meaning translation ·

Explanation

The meaning in a few plain lines

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye pe dajudaju Ọlọhun pa a laṣẹ nibi irun ki o fi oríkèé meje ninu awọn oríkèé ara rẹ kan'lẹ; awọn naa ni: Alakọkọọ: Iwaju ori: Oun ni: Alawẹ oju ti o wa ni oke imu ati oju mejeeji, Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a, fi ọwọ rẹ si imu rẹ, ti o fihan pe iwaju ati imu jẹ ọkan ninu awọn meje naa, o si tẹnumọ pe ẹni ti o n fi ori kan ilẹ maa fi kan ilẹ pẹlu imu rẹ. Oríkèé kejì ati ìkẹta: Ọwọ mejeeji. Ẹlẹẹkẹrin ati Ẹlẹẹkarun-un: Orunkun mejeeji. Ẹlẹẹkẹfa ati Ẹlẹẹkeje: Awọn ọmọ ika ẹsẹ mejeeji. O si tun pa wa laṣẹ ki a ma so awọn irun wa, ki a si ma ka awọn aṣọ wa papọ nibi iforikanlẹ lati fi da aabo bo o; bi ko ṣe pe a maa da a silẹ titi ti yio fi kan ilẹ, nitori naa yio le'lẹ pẹlu awọn orikee ara naa.

Source
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Download image

Saved at original quality