Hadith for the World
Tap the image to view it full size
Fik'hu ati ìpìlẹ̀ rẹ

Lati ọdọ Abu Hurayra – ki Ọlọhun yọnu si i – o sọ pe:

Available in 65 languages
«Lati ọdọ Abu Hurayra – ki Ọlọhun yọnu si i – o sọ pe: Arakunrin afọju kan wa ba Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, o wa sọ pe: Irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun, ko si ẹni ti yio fa mi wa si mọṣalaṣi, ni o wa bi Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – leere ki o ṣe ẹdẹ fun un ki o maa kirun ni inu ile rẹ, ni o wa ṣe ẹdẹ fun un, nigba ti o wa yi ẹyin pada, o pe e, o wa sọ fun un pe: «Njẹ o maa n gbọ ipe irun?» O sọ pe: Bẹẹ ni, o sọ pe: «Ki o ya dahun».»

Meaning translation ·

Explanation

The meaning in a few plain lines

Arakunrin afọju kan wa ba Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, o wa sọ pe: Irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun, ko si lọdọ mi ẹni ti o le maa ran mi lọwọ ti yio si maa fa mi wa si mọṣalaṣi ni asiko awọn irun maraarun, o n wa lati ọdọ Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – ki o ṣe ẹdẹ fún un nibi gbigbe irun janmọọn ju silẹ, nigba naa ni o wa ṣe ẹdẹ fun un, nigba ti o wa yi ẹyin pada, o pe e, o wa sọ fun un pe: Njẹ o maa n gbọ ipe irun? O sọ pe: Bẹẹ ni, o sọ pe: Ki o yaa jẹ ipe oluperun.

Source
Muslim gba a wa
Download image

Saved at original quality