Hadith for the World
Tap the image to view it full size
Fik'hu ati ìpìlẹ̀ rẹ

Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo gbọ́ ti Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe:

Available in 64 languages
«Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo gbọ́ ti Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe: “Adamọ marun-un lo jẹ: Dida abẹ ati fifa irun abẹ ati gige tubọmu ati gige awọn èékánná ati fifa irun abiya”.»

Meaning translation ·

Explanation

The meaning in a few plain lines

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe awọn iwa marun-un kan n bẹ ninu ẹsin Isilaamu ati ninu sunnah awọn ojiṣẹ: Akọkọ nibẹ ni: Dida abẹ, oun ni gige awọ ti o lekun lori nnkan ọmọkunrin lori adenderi, ati gige ori awọ ti o wa lori oju ara obinrin lori aye ibi ti nnkan ọmọkunrin maa n wọle si. Ikeji nibẹ ni: Fifa irun abẹ, oun ni irun oju ara ti o wa ni àyíká oju ara. Ikẹta nibẹ ni: Gige tubọmu, oun ni gige nnkan ti o hù jade lori ete ọkunrin oke nibi ti ete ti maa hàn. Ikẹrin nibẹ ni: Gige awọn èékánná. Ikarun-un nibẹ ni: Gige irun abiya.

Source
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Download image

Saved at original quality