Hadith for the World
Tap the image to view it full size
Àwọn ìwà dáadáa ati awọn ẹkọ

Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe:

Available in 60 languages
«Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Ẹ ko lee wọ alujanna titi ti ẹ fi maa gbagbọ, ati pe e ko lee gbagbọ titi ti ẹ fi máa nífẹ̀ẹ́ ara yin, ẹ wa jẹ ki n juwe yin si nkankan ti o jẹ pe ti ẹ ba ṣe e ẹ máa nífẹ̀ẹ́ ara yin? Ẹ maa tan salamọ ka laarin ara yin».»

Meaning translation ·

Explanation

The meaning in a few plain lines

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye pe dajudaju ẹnikankan o lee wọ alujanna ayaafi muumini, ati pe igbagbọ o lee pe ati pe ìṣesí awujọ musulumi o lee daa titi ti wọn o fi nífẹ̀ẹ́ ara wọn. Lẹyin naa ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa juwe lọ sibi eyiti o lọla julọ ninu awọn alamọri eyiti o ṣe pe pẹlu rẹ ni ifẹ fi maa n kari, oun naa ni fifọn salamọ ka laarin awọn musulumi, eleyii ti Ọlọhun ṣe ni kiki fun awọn ẹru Rẹ.

Source
Muslim gba a wa
Download image

Saved at original quality