Hadith for the World
Tap the image to view it full size
Àwọn ìwà dáadáa ati awọn ẹkọ

Lati ọdọ Sulaiman ọmọ Suradin - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ bayi pe:

Available in 53 languages
«Lati ọdọ Sulaiman ọmọ Suradin - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ bayi pe: Mo wa lori ijoko pẹlu Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) nigbati awọn arakunrin meji nbu arawọn, ojú ọkan nínú àwọn mejeeji pọ́n kankan, bẹẹni iṣan parikẹ rẹ naa ntana jade, bayi ni Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Re máa ba a) sọ pé: "Dajudaju ẹmi mọ gbólóhùn kan, ti o ba le wi i ni, nkan ti nbi ninu yóò sakuro lọdọ rẹ "ti o ba le sọ pé: "mo wa iṣọ lọdọ Ọlọhun nipa aburu èṣù" (Satani), ibinu ti nbi náà yóò lọ ni wọ́n bá sọ fún un pe: dajudaju Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a) sọ pe: "yáa wá isọra pẹlu Ọlọhun nipa èṣù" (Satani), Arakunrin náà bá dahun pe: Se weere kọlu mi ni bi?»

Meaning translation ·

Explanation

The meaning in a few plain lines

Arakunrin meji njà lọdọ Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a), bẹẹ ni oju ọkan ninu awọn mejeeji ti pọ́n koko, bẹẹ ni isan to yipo ọrun rẹ ti ran jáde. Ni ojisẹ Ọlọhun (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) bá sọ pé: Dajudaju emi mọ gbólóhùn kan ti ẹni to nbinu yii bá wí i, ibinu naa yóò sa kuro fun, ti o ba le sọ pé: mo sa di Ọlọhun nibi aburu èṣù (Satani) ẹni ẹkọ ẹni egbe. Wọ́n sọ fun un pe: Dajudaju Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) sọ pe: Wá isọra pẹlu Ọlọhun nipa èṣù (Satani). Ni o ba dahun, o ni: se were ni mi bi?! o le ro pe ẹnikan kò nii wá isọra nipa èṣù (Satani) ayáafi ẹni tí o ba ya were.

Source
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Download image

Saved at original quality