Hadith for the World
Tap the image to view it full size
Àwọn ìwà dáadáa ati awọn ẹkọ

Lati ọdọ Abu Hurairah - ki Ọlọhun yọnu si i - ó sọ pé: Mo gbọ Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - tí ń sọ pé:

Available in 71 languages
«Lati ọdọ Abu Hurairah - ki Ọlọhun yọnu si i - ó sọ pé: Mo gbọ Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - tí ń sọ pé: "Etọ Musulumi lori Musulumi miiran márùn-ún ni: Dídá salamọ pada, bibẹ alaarẹ wò, titẹle ìsìnkú, didahun ipepe, ṣiṣadura fun ẹniti ó bá sín".»

Meaning translation ·

Explanation

The meaning in a few plain lines

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n ṣe alaye diẹ ninu awọn ẹtọ Musulumi lori Musulumi ẹgbẹ́ rẹ̀, Àkọ́kọ́ nínú àwọn ẹ̀tọ́ wọ̀nyí ni dídá salamọ padà si ẹniti ó bá salamọ si ọ. Ẹtọ keji: ṣiṣe abẹwo si alaaarẹ. Ẹtọ kẹta: Títẹ̀lé ìsìnkú láti ilé rẹ̀ titi de àyè ikirun si oku lara, titi de ibi saare rẹ̀, titi tí wọ́n ó fi sin in. Ẹtọ kẹrin: Dídáhùn ipepe bí ó bá pè é síbi àpèjẹ ìgbéyàwó àti awọn ǹkan mìíràn. Ẹtọ karùn-ún: Ṣiṣadura fun ẹniti ó bá sín, iyẹn ni pe kí ó sọ fun un nigba ti ó bá ti sọ pe ALHAMDULILLAH lẹyin sínsín: YARHAMUKALLAH, lẹyin naa ni ẹniti ó sín ó sọ pe: YAHDIKUMULLAHU WA YUSLIHU BAALAKUM.

Source
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Download image

Saved at original quality