Hadith for the World
Tap the image to view it full size
Àwọn ìwà dáadáa ati awọn ẹkọ

Lati ọdọ Abu Mūsa - ki Ọlọhun yọnu si i - lati ọdọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o sọ pe:

Available in 59 languages
«Lati ọdọ Abu Mūsa - ki Ọlọhun yọnu si i - lati ọdọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o sọ pe: «Dajudaju Ọlọhun ti O biyi ti O gbọnngbọn maa n tẹ ọwọ Rẹ ni oru lati gba tuuba ẹni ti o ba da ẹṣẹ ni ọsan, O si tun maa n tẹ ọwọ Rẹ ni ọsan lati gba tuuba ẹni ti o da ẹṣẹ ni oru titi oorun o fi yọ ni ibi ti o ti maa n wọ».»

Meaning translation ·

Explanation

The meaning in a few plain lines

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n funni ni iro pe: Dajudaju Ọlọhun ti ọla Rẹ ga maa n gba tituuba awọn ẹru rẹ, ti ẹru ba da ẹṣẹ kan ni ọsan ti o si tuuba ni oru Ọlọhun o gba tuuba rẹ, ti o ba si da ẹsẹ ni oru ti o wa tuuba ni ọsan Ọlọhun a gba tuuba rẹ, Ọba ti mimọ n bẹ fun Un maa n tẹ ọwọ Rẹ fun tuuba ni ti ìdùnnú si i ati gbigba a, ati pe ilẹkun tituuba o yẹ ni nkan ti wọn maa ṣi silẹ titi oorun o fi yọ nibi ti o ti n wọ ni ti ikede titan ayé, ti o ba ti wa yọ dajudaju ilẹkun tituuba ti di titi niyẹn.

Source
Muslim gba a wa
Download image

Saved at original quality