Hadith for the World
Tap the image to view it full size
Adisọkan

Lati ọdọ Abu Barzata Al-aslamiy - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe:

Available in 61 languages
«Lati ọdọ Abu Barzata Al-aslamiy - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Ẹsẹ mejeeji ẹru kan ko nii yẹ ni ọjọ igbedide titi ti wọn o fi bi i nipa ọjọ ori rẹ nibo ni o pari rẹ si, ati nipa imọ rẹ kini o fi ṣe, ati nipa dukia rẹ nibo ni o ti ko o jọ ati pe nibo ni o na an si, ati nipa ara rẹ nibo ni o lo o si».»

Meaning translation ·

Explanation

The meaning in a few plain lines

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - funni niroo pe dajudaju ẹnikẹni ninu awọn eeyan ko nii tayọ aaye iṣiro iṣẹ ni ọjọ igbedide lọ si alijanna tabi ina titi ti wọn o fi bi i nipa awọn alamọri kan: Alakọkọọ: Iṣẹmi rẹ nibo ni o pari rẹ sí? Ẹlẹẹkeji: Imọ rẹ njẹ o wa a nitori ti Ọlọhun? Ati pe njẹ o fi ṣiṣẹ ṣe? Ati pe njẹ o mu un de ọdọ ẹni ti o lẹtọọ si i? Ẹlẹẹkẹta: Dukia rẹ nibo ni o ti ko o jọ ṣe nibi ẹtọ ni abi níbi eewọ? Ati pe nibo ni o na an si, ṣe ibi nkan ti o yọ Ọlọhun ninu ni abi ibi ti o bi I ninu? Ẹlẹẹkẹrin: Ara rẹ ati agbara rẹ ati alaafia rẹ ati ọdọ rẹ nibo ni o lo o si?

Source
Tirmiziy ni o gba a wa
Download image

Saved at original quality