Hadith for the World
Tap the image to view it full size
Fik'hu ati ìpìlẹ̀ rẹ

Lati ọdọ Ibnu Umar- ki Ọlọhun yọnu si àwọn mejeeji- o sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:

Available in 70 languages
«Lati ọdọ Ibnu Umar- ki Ọlọhun yọnu si àwọn mejeeji- o sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Jibril kò yẹ̀ kò gbò ni ẹni tí n sọ àsọtẹ́lẹ̀ fun mi nipa aládùúgbò, titi ti mo fi lérò pé yoo mu u jogún”.»

Meaning translation ·

Explanation

The meaning in a few plain lines

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe Jibril ko yẹ ni ẹni tí n pààrà fun un ti o si n pa a láṣẹ láti ni akolekan aládùúgbò ti ilé rẹ sunmọ, Mùsùlùmí ni tabi Kèfèrí, mọlẹbi ni tabi ẹni tí kii ṣe mọ̀lẹ́bí, pẹlu ṣiṣọ iwọ̀ rẹ, ki eeyan ma si fi suta kan an, ki èèyàn si maa ṣe daadaa si i, ki èèyàn si maa ṣe suuru lori suta rẹ, titi ti Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- fi lérò pe imisi maa sọ̀kalẹ̀ pé ki a maa fun un ninu dúkìá aládùúgbò rẹ ti o ba fi silẹ lẹ́yìn iku rẹ latara bi o ṣe bàbàrà iwọ̀ rẹ, ati bi Jibril ṣe n pààrà rẹ.

Source
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Download image

Saved at original quality