Hadith for the World
Tap the image to view it full size
Àwọn ìwà dáadáa ati awọn ẹkọ

Lati ọdọ Khaolah Al-Ansaariyyah- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Mo gbọ ti Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé:

Available in 70 languages
«Lati ọdọ Khaolah Al-Ansaariyyah- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Mo gbọ ti Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé: “Dájúdájú àwọn èèyàn kan n wọ inu dúkìá Ọlọhun ni ọ̀nà tí kò tọ́, wọn maa wọ iná ni Ọjọ́ Àjíǹde”.»

Meaning translation ·

Explanation

The meaning in a few plain lines

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ nipa awọn eeyan kan ti wọn n ṣe ibajẹ ninu dúkìá àwọn Musulumi, ti wọn si n mu u ni ọ̀nà ti kò tọ́, eyi ni itumọ kan ti o kari nibi dukia, nibi kiko o jọ lati ibi ti ko ti ni ẹtọ, ati nina an sibi ti kii ṣe aaye rẹ ti o tọ, jíjẹ dúkìá àwọn ọmọ orukan maa wọ inú ẹ, àti awọn dúkìá ti a fi sọri awọn kan, ati titako agbafipamọ, ati mimu ninu dúkìá gbogbogboo ni ọ̀nà tí kò tọ́. Lẹ́yìn náà ni Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pé ẹsan wọn ni iná ni Ọjọ́ Àjíǹde.

Source
Bukhaariy gba a wa
Download image

Saved at original quality