Hadith for the World
Tap the image to view it full size
Fik'hu ati ìpìlẹ̀ rẹ

Láti ọ̀dọ̀ Jundub ọmọ Abdullahi Al-Qasriy- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:

Available in 70 languages
«Láti ọ̀dọ̀ Jundub ọmọ Abdullahi Al-Qasriy- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ẹni tí ó bá ki irun asunbaa, onítọ̀hún ti wa nínú ààbò Ọlọhun, nítorí náà ẹ ṣọ́ra ki Ọlọhun ma baa bi yin leere nǹkan kan ninu ààbò Rẹ̀; torí ẹni ti Ọlọhun ba bi leere nǹkan kan nínú ààbò Rẹ̀, yoo gba ẹsan lara rẹ, yoo si da ojú rẹ bo ilẹ̀ ninu ina Jahannama”.»

Meaning translation ·

Explanation

The meaning in a few plain lines

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé ẹni tí o ba ki irun alufajari ti wa ninu iṣọ Ọlọhun ati ààbò Rẹ, yoo maa da aabo bo o, yoo si maa ṣẹ́gun fun un. Lẹyin naa ni Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa ṣọ wa lara kúrò nibi títú àdéhùn naa ati biba a jẹ́, yálà pẹlu gbigbe irun alufajari ju silẹ ni, tabi ìkọlù ẹni ti n ki i, ẹni tí ó bá ṣe iyẹn ti ba ààbò yii jẹ́, o si ni ẹtọ si àdéhùn ìjìyà ti o le koko pẹ̀lú pe ki Ọlọhun bi i leere nípa ohun tí o ṣe àṣeètó nibẹ nibi ẹtọ Rẹ, ẹni tí Ọlọhun ba bi léèrè, yoo gba ẹsan lara rẹ, lẹ́yìn náà yoo da oju rẹ bo ilẹ̀ ninu iná.

Source
Muslim gba a wa
Download image

Saved at original quality