Hadith for the World
Tap the image to view it full size
Àwọn ìwà dáadáa ati awọn ẹkọ

Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé:

Available in 70 languages
«Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Wọn bi ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- leere nipa nǹkan ti o maa mu awọn èèyàn wọ alujanna julọ, o sọ pe: “Ìpayà Ọlọhun ati iwa dáadáa”, wọn tun bi i leere nipa nnkan ti o maa mu awọn èèyàn wọ ina julọ, o sọ pe: “Ẹnu ati Abẹ”.»

Meaning translation ·

Explanation

The meaning in a few plain lines

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe eyi ti o tobi ju ninu awọn okùnfà ti yoo mu èèyàn wọ alujanna méjì ni, àwọn naa ni: Ipaya Ọlọhun ati iwa dáadáa. Ìpayà Ọlọhun: Oun ni ki o fi aabo si aarin rẹ ati iya Ọlọhun, pẹ̀lú ṣíṣe àwọn nǹkan ti O pàṣẹ lati ṣe, ati jíjìnnà si awọn nǹkan ti O kọ̀. Iwa dáadáa: O maa jẹ pẹlu títú ojú ká, ati ṣíṣe dáadáa, ati ki èèyàn ma jẹ ki suta kan ẹlòmíràn. Eyi ti o tobi ju ninu awọn okùnfà ti yoo mu awọn èèyàn wọ ina meji ni, àwọn naa ni: Ahọn ati Abẹ́. Lara àwọn ẹṣẹ ahọ́n ni: Irọ́, ọ̀rọ̀-ẹ̀yìn, òfófó, ati awọn mìíràn. Lara àwọn ẹṣẹ abẹ́ ni: Ṣìná, ati ibalopọ láàrin ọkùnrin si ọkùnrin, ati awọn mìíràn.

Source
Tirmiziy ati Ibnu Maajah ati Ahmad ni wọ́n gba a wa
Download image

Saved at original quality