Hadith for the World
Tap the image to view it full size
Àwọn ìwà dáadáa ati awọn ẹkọ

Láti ọ̀dọ̀ Muaawiyah- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo gbọ ti Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé:

Available in 66 languages
«Láti ọ̀dọ̀ Muaawiyah- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo gbọ ti Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé: “Ẹni tí Ọlọhun ba fẹ́ oore fun, yoo fun un ni agbọye ninu ẹsin, olùpín ni mi, Ọlọhun ni n fúnni, ìjọ yii ko nii dẹkun lati maa duro lori àṣẹ Ọlọhun, ti ẹni tí ó bá yapa wọn ko si nii ko ìpalára ba wọn, titi ti àṣẹ Ọlọhun yoo fi dé”.»

Meaning translation ·

Explanation

The meaning in a few plain lines

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé ẹni tí Ọlọhun ba fẹ oore fun, O maa fun un ni agbọye ninu ẹsin Rẹ, oun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- si ni olupin, o maa n pin ohun ti Ọlọhun ba fun un ninu arisiki ati imọ ati awọn nǹkan mìíràn, ati pe ẹni ti n fúnni gan ni Ọlọhun, ṣùgbọ́n àwọn tí wọ́n o kii ṣe olohun jẹ okùnfà ti ko lee ṣe anfaani kankan ayafi pẹ̀lú iyọnda Ọlọhun, ìjọ yii ko nii dẹkun lati maa duro lori àṣẹ Ọlọhun, ti ẹni tí ó bá yapa wọn ko si nii ko ìpalára ba wọn, titi ti ayé fi maa parẹ”

Source
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Download image

Saved at original quality