Hadith for the World
Tap the image to view it full size
Àwọn ìwà dáadáa ati awọn ẹkọ

Láti ọ̀dọ̀ Khaolat ọmọbìnrin Hakiim As-Sulamiyyah, o sọ pe: Mo gbọ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe:

Available in 66 languages
«Láti ọ̀dọ̀ Khaolat ọmọbìnrin Hakiim As-Sulamiyyah, o sọ pe: Mo gbọ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe: “Ẹni ti o ba sọkalẹ si ààyè kan, ti o wa sọ pé: AUUZU BIKALIMAATIL LAAHIT-TAMMAATI MIN SHARRI MAA KHỌLAK, nǹkan kan ko nii ni in lara titi ti yoo fi kuro ni aaye rẹ yẹn”.»

Meaning translation ·

Explanation

The meaning in a few plain lines

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n tọ ìjọ rẹ sọ́nà lọ sibi ìdìrọ̀mọ́ ati ìsádi ti o maa ṣe àǹfààní ti gbogbo nnkan ti a n ṣọ́ra fun ti èèyàn n bẹ̀rù maa lọ pẹ̀lú rẹ nígbà tí ó bá sọ̀kalẹ̀ si ààyè kan lórí ilẹ̀, boya o wa ni ìrìn-àjò ni, tabi ìjáde ìgbafẹ́, tabi ohun ti o yatọ si ìyẹn: Pẹ̀lú pe ki o dìrọ̀ mọ́ ki o si sádi àwọn gbólóhùn Ọlọhun ti o pe nibi ọla rẹ ati ibukun rẹ ati àǹfààní rẹ, eyi ti o la kuro nibi gbogbo àléébù, níbi aburu gbogbo ẹ̀dá ti o ni aburu lára, ọkàn rẹ maa wa balẹ ni ààyè yẹn nibi gbogbo nnkan ti o ba le ṣe e ni suta lópin ìgbà tí o ba ṣi wa nibẹ.

Source
Muslim gba a wa
Download image

Saved at original quality