Hadith for the World
Tap the image to view it full size
Adisọkan

Lati ọdọ Abu Hurairah, ki Ọlọhun yọnu si i, o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, sọ pe:

Available in 65 languages
«Lati ọdọ Abu Hurairah, ki Ọlọhun yọnu si i, o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, sọ pe: “Igbagbọ jẹ ipin aadọrin ati nnkankan- tabi ọgọta ati nnkankan-, eyi ti o ni ọla julọ nibẹ ni gbolohun Laa ilaaha illallohu, eyi ti o kere julọ nibẹ ni mimu suta kuro lọna, ati pe itiju jẹ ipin kan ninu igbagbọ”.»

Meaning translation ·

Explanation

The meaning in a few plain lines

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe dajudaju igbagbọ jẹ awọn ipin kan ati awọn iwa ti wọn pọ, o ko awọn iṣẹ ati awọn adisọkan ati awọn ọrọ kan sinu. Ati pe eyi to ga julọ ninu iwa igbagbọ ti o si daa julọ nibẹ ni gbolohun: “Laa ilaaha illallohu”, ni mimọ ìtumọ̀ rẹ, ni ṣíṣe iṣẹ pẹlu nnkan ti o da le lori, bii pe dajudaju Ọlọhun ni Ọlọhun Ọba Ọkan ṣoṣo ti O lẹtọọ si ijọsin ni Oun nikan ṣoṣo yatọ si ẹni ti o yatọ si I. Ati pe eyi ti o kere julọ ninu awọn iṣẹ igbagbọ ni mimu gbogbo nnkan ti o le ko suta ba awọn eniyan kuro ni awọn oju ọna wọn. Lẹyin naa Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju itiju wa ninu iwa igbagbọ, oun ni awọn iwa kan ti o maa n muni ṣe nǹkan daadaa, ti o si maa n muni gbé iwa buruku ju silẹ.

Source
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Download image

Saved at original quality