Hadith for the World
Tap the image to view it full size
Kuraani Alapọn-ọnle ati àwọn imọ rẹ

Lati ọdọ Ubay ọmọ Kahb- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:

Available in 70 languages
«Lati ọdọ Ubay ọmọ Kahb- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Irẹ Abu Al-Munzir, ǹjẹ́ o mọ aaya wo ninu tira Ọlọhun ti o wa pẹlu rẹ ni o tobi julọ?”, o sọ pe: Mo sọ pé: Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ ni wọn ni imọ julọ. O sọ pe: “Irẹ Abu Al-Munzir, ǹjẹ́ o mọ aaya wo ninu tira Ọlọhun ti o wa pẹlu rẹ ni o tobi julọ?”, o sọ pe: Mo sọ pé: {Allāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun, Alààyè, Alámòjúútó-ẹ̀dá} [Al-Baqarah: 255]. O sọ pe: O wa fi ọwọ́ lu mi láyà, o wa sọ pé: “Mo fi Ọlọhun búra, o kú oriire imọ naa, ki Ọlọhun ṣe e ni irọrun fun ẹ, irẹ Abu Al-Mundhir”.»

Meaning translation ·

Explanation

The meaning in a few plain lines

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- bi Ubay ọmọ Kahb léèrè nipa aaya ti o tobi ju ninu tira Ọlọhun, o wa ṣe iyèméjì nibi dáhùn, lẹ́yìn náà ni o wa sọ pé: Oun ni aayatul Kursiyy: {Allāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun, Alààyè, Alámòjúútó-ẹ̀dá}, Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa ṣe atilẹyin fun un, Anọbi wa lu u ni àyà lati tọka si pe o kún fun imọ ati ọgbọ́n, o wa ṣe adua fun un pe ki o maa dunnu pẹ̀lú imọ yii ki o si rọrùn fún un.

Source
Muslim gba a wa
Download image

Saved at original quality