Hadith for the World
Tap the image to view it full size
Fik'hu ati ìpìlẹ̀ rẹ

Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe:

Available in 60 languages
«Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jẹ ẹni ti maa n ṣe adua ti o si maa n sọ pe: «Irẹ Ọlọhun dajudaju emi wa iṣọra pẹlu Rẹ kuro nibi iya saare, ati nibi iya ina, ati nibi fitina iṣẹmi ati iku, ati nibi fitina al-Masiihu ad-Dajjāl». Nibi ti gbolohun ti Muslim: «Ti ẹnikẹni ninu yin ba ti pari ataaya igbẹyin, ki o yaa wa iṣọra pẹlu Ọlọhun kuro nibi awọn nkan mẹẹrin: Nibi iya jahannamọ, ati nibi iya saare, ati nini fitina iṣẹmi ati iku, ati nibi aburu al-Masiihu ad-Dajjāl».»

Meaning translation ·

Explanation

The meaning in a few plain lines

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jẹ ẹni ti maa n wa iṣọra pẹlu Ọlọhun kuro nibi nkan mẹẹrin, lẹyin ataaya igbẹyin ati siwaju salamọ ninu irun, o si tun pa wa laṣẹ ki a maa wa iṣọra pẹlu Ọlọhun kuro nibẹ, Ikinni: Nibi iya saare. Ẹẹkeji: Nibi iya ina ati pe ìyẹn ni ọjọ igbedide. Ẹẹkẹta: Nibi fitina iṣẹmi bi awọn adun aye ti o jẹ eewọ ati awọn iruju ti maa n sọni nu, ati nibi fitina iku, ìyẹn ni àsìkò pipọka iku, bii yiyẹ kuro ninu Isilaamu tabi Sunnah, tabi fitina saare gẹgẹ bii ibeere awọn malaika mejeeji. Ẹẹkẹrin: Fitina al-Masiihu ad-Dajjāl eleyii ti yio jade ni igbẹyin aye, Ọlọhun yio fi i dan awọn ẹru Rẹ wo; o wa darukọ rẹ lọ́tọ̀ latari titobi fitina rẹ ati isọninu rẹ.

Source
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Download image

Saved at original quality