Hadith for the World
Tap the image to view it full size
Adisọkan

Lati ọdọ Abu Hurairah, ki Ọlọhun yọnu si i, o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, sọ pe:

Available in 70 languages
«Lati ọdọ Abu Hurairah, ki Ọlọhun yọnu si i, o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, sọ pe: “Ọlọhun, Oníbùkún ti O ga jùlọ, sọ pe: Èmi ni Olùrọrọ̀ julọ tayọ níní orogún. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ kan, ti o mu orogun ninu rẹ̀ pẹlu Èmi Ọlọhun, Emi yóò fi òun àti orogun rẹ̀ sílẹ̀.»

Meaning translation ·

Explanation

The meaning in a few plain lines

Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, n fun wa ni iro pe: Ọlọhun, Onibukun ti O ga julọ sọ pe: Òun ni Olùrọrọ̀ julọ tayọ níní orogún, Òun ni Ẹni tí Ó rọrọ̀ tayọ gbogbo nkan, ati pe ti eniyan bá ṣe iṣẹ ijọsin kan, ti o sì ṣe e fun Ọlọhun ati ohun miiran tó yatọ si Ọlọhun; Ọlọ́hun yoo gbe e ju sílẹ̀, kò nii gbà á lọ́wọ́ rẹ̀, yoo sì dá a padà fún un. Nitori naa, ọranyan ni ki iṣẹ́ jẹ́ mimọ fun Ọlọ́hun Ọba Aleke ọla, nítorí pé, Ọlọ́hun – mimọ fun Un – kò nii gba iṣẹ kan ayafi eyiti ó jẹ́ mimọ lati lè fi ri ojú rere Rẹ̀.

Source
Muslim gba a wa
Download image

Saved at original quality