Hadith for the World
Ìgbàgbọ́ ninu Ọlọhun ti O lágbára ti O gbọnngbọn

Taohiid ti uluuhiyyah

14 hadiths

14 hadiths

Lati ọdọ Umar ọmọ Al-Khattaab- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Dajudaju Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- kọ fun yin lati maa bura pẹlu awọn baba yin", Umar sọ pe: Mo fi Ọlọhun bura, mi ko bura pẹlu rẹ lati igba ti mo ti gbọ́ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti kọ kuro nibẹ ni ti ẹni ti o mọọmọ tabi ni ẹni tí ó gbé ìbúra ẹlòmíràn pẹ̀lú rẹ wa.Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Lati ọdọ Abu Hurairah, ki Ọlọhun yọnu si i, o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, sọ pe: “Ọlọhun, Oníbùkún ti O ga jùlọ, sọ pe: Èmi ni Olùrọrọ̀ julọ tayọ níní orogún. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ kan, ti o mu orogun ninu rẹ̀ pẹlu Èmi Ọlọhun, Emi yóò fi òun àti orogun rẹ̀ sílẹ̀.Muslim gba a wa
Lati ọdọ Umar ọmọ Al-Khattab - ki Ọlọhun yọnu si i - ó sọ pé: Mo gbọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - tí ń ṣo pé: "Ẹ má ṣe yìn mi jù gẹgẹ bi awọn Kristẹni ṣe yin ọmọ Maria jù; ẹrú Ọlọhun ni ẹmi n ṣe, nitori naa, ẹ wi pe: Ẹru Ọlọhun ati Ojiṣẹ Rẹ̀".Bukhaariy gba a wa
Lati ọdọ Abu Hurairah - ki Ọlọhun yọnu si i - dajudaju ó sọ pé: Wọ́n sọ pé: Iwọ Ojiṣẹ Ọlọhun, ta ni yoo ṣoriire jù ninu awọn eniyan pẹlu ìṣìpẹ̀ rẹ ni ọjọ Igbende? Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - dahun bayii wi pe: "Irẹ Abu Hurairah, mo ti rò naa pé ko si ẹnikan ti yoo bi mi leere nipa hadiisi yii saaju rẹ, nigba ti mo ti ri itaraṣaṣa rẹ si imọ hadiisi, Ẹnití ó maa ṣoriire jù pẹlu ìṣìpẹ̀ mi ní ọjọ Igbende, oun ni ẹniti ó bá sọ pé ko si ọlọhun miran ayafi Ọlọhun Allah, tí ó ṣo bẹẹ pẹlu ododo lati inu ọkàn rẹ̀".Bukhaariy gba a wa
Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Mas'ud- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ ọrọ kan, emi naa sọ omiran, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Ẹni ti o ba ku ti o si n pe akẹgbẹ kan ti o yàtọ̀ si Ọlọhun, o maa wọ ina" emi naa sọ pe: Ẹni ti o ba ku, ti ko si kii n pe akẹgbẹ kan mọ Ọlọhun, o maa wọ alujanna.Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
عن ابن مسعود رضي الله عنه قال: قال رسول الله صلى الله عليه وسلم : «من أصابته فَاقَة فأنْزَلها بالناس لم تُسَدَّ فَاقَتُهُ، ومن أنْزَلها بالله، فَيُوشِكُ الله له بِرزق عاجل أو آجل».رواه أبو داود والترمذي وأحمد
عن عبد الله بن مسعود رضي الله عنه عن النبي صلى الله عليه وسلم أنه قال: "أكبر الكبائر: الإشراك بالله، والأمن من مَكْرِ الله، والقُنُوطُ من رحمة الله، واليَأْسُ من رَوْحِ الله".رواه عبد الرزاق
عن عبد الله بن عكيم رضي الله عنه مرفوعاً: «مَنْ تَعَلَّقَ شيئا وُكِلَ إليه».رواه أحمد والترمذي
Lati ọdọ Tooriq ọmọ Ashyam Al-Ash-ja'iy- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo gbọ ti Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe: “Ẹni ti o ba sọ pe: LAA ILAAHA ILLALLOHU, ti o wa ṣe aigbagbọ pẹlu nnkan ti wọn n jọsin fun yatọ si Ọlọhun, dukia rẹ ati ẹjẹ rẹ ti jẹ eewọ, ati pe ìṣirò rẹ wa lọ́wọ́ Ọlọhun”.Muslim gba a wa
Lati ọdọ Abu Marthad Al-ganawiy – ki Ọlọhun yọnu si i– o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pe: «Ẹ ma ṣe jokoo si ori awọn sàréè, ẹ ko si gbọdọ kirun si i lara».Muslim gba a wa
Lati ọdọ 'Aaisha iya awọn olugbagbọ- ki Ọlọhun yọnu si i-: Dajudaju Ummu Salamah dárúkọ ṣọọṣi kan ti o ri ni ilẹ̀ Habasha fun ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, wọn n pe e ni Maariyah, o wa sọ nnkan ti o ri nibẹ fun un ninu awọn aworan, ni ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pe: "Awọn wọnyẹn ni ìjọ kan, ti ẹru rere ba ku ninu wọn tabi ọkùnrin rere, wọn maa kọ mọsalasi kan sori saare rẹ, wọn yoo si ya awọn aworan yẹn síbẹ̀, awọn wọnyẹn ni awọn ti wọn buru julọ ninu ẹda lọdọ Ọlọhun".Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Lati ọdọ Mu’aadh- ki Ọlọhun yọnu si i-, o sọ pe: Mo wa lẹyin Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lori kẹtẹkẹtẹ kan ti wọn n pe ni ‘Ufair, o sọ pe: “Irẹ Mu’aadh, njẹ o mọ iwọ Ọlọhun lori awọn ẹrusin Rẹ, ati nnkan ti o jẹ iwọ àwọn ẹrusin lori Ọlọhun?”, mo sọ pe: Ọlọhun ati Ojiṣẹ Rẹ ni wọn ni imọ julọ, o sọ pe: “Dajudaju iwọ Ọlọhun lori awọn ẹrusin ni ki wọn maa jọsin fun Un ki wọn si ma da nnkan pọ mọ Ọn ninu ẹbọ, iwọ àwọn ẹrusin lori Ọlọhun ni ki O ma fi iya jẹ ẹni ti ko ba da nnkan pọ mọ Ọn ninu ẹbọ”, mo sọ pe: Irẹ Òjíṣẹ́ Ọlọhun, ṣe ki n maa fun awọn eniyan ni iro idunnu nipa rẹ? O sọ pe: “Rara, ma fun wọn ni iro ìdùnnú, ki wọn ma baa gbára lé e”.Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Lati ọdọ Jabir- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Arakunrin kan wa ba Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: Irẹ Òjíṣẹ́ Ọlọhun, ki ni nnkan meji naa ti wọn maa n sọ nǹkan di dandan? O sọ pe: “Ẹni ti o ba ku ti ko da ẹbọ kankan pọ mọ Ọlọhun yoo wọ alujanna, ẹni ti o ba si ku ti o da ẹbọ pọ mọ Ọlọhun yoo wọ ina".Muslim gba a wa
عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رضي الله عنه قَالَ: قَالَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ: «إِنَّ اللهَ يَرْضَى لَكُمْ ثَلَاثًا، وَيَكْرَهُ لَكُمْ ثَلَاثًا، فَيَرْضَى لَكُمْ: أَنْ تَعْبُدُوهُ، وَلَا تُشْرِكُوا بِهِ شَيْئًا، وَأَنْ تَعْتَصِمُوا بِحَبْلِ اللهِ جَمِيعًا وَلَا تَفَرَّقُوا، وَيَكْرَهُ لَكُمْ: قِيلَ وَقَالَ، وَكَثْرَةَ السُّؤَالِ، وَإِضَاعَةِ الْمَالِ».رواه مسلم