Hadith for the World
Tap the image to view it full size
Fik'hu ati ìpìlẹ̀ rẹ

Lati ọdọ Ma'daan ọmọ Abu Tolha Al-Ya'mariy o sọ pe:

Available in 59 languages
«Lati ọdọ Ma'daan ọmọ Abu Tolha Al-Ya'mariy o sọ pe: Mo pade Thaobaan ẹru ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- mo wa sọ pe: Fun mi ni iro nipa iṣẹ kan ti mo ba n ṣe e Ọlọhun maa fi mu mi wọnu alujanna? Tabi o sọ pe mo sọ pé: pẹlu eyi ti Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ si julọ ninu awọn iṣẹ, o ba dakẹ. Lẹ́yìn naa mo bi i leere ni o ba dakẹ. Lẹ́yìn naa mo bi i leere ni ẹẹketa, o wa sọ pe: Mo beere nipa ìyẹn lọwọ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, o sọ pe: Fiforikanlẹ fun Ọlọhun lọpọlọpọ jẹ dandan fun ẹ, dajudaju o ko nii forikanlẹ fun Ọlọhun ni iforikanlẹ ẹẹkan, afi ki Ọlọhun fi gbé ẹ ga nipo, ki O si fi ba ẹ pa ẹṣẹ rẹ" Ma'daan sọ pe: Lẹyin naa mo pade Abu Dardaa mo si bi i leere, o si sọ fun mi: Iru nnkan ti Thaobaan sọ fun mi.»

Meaning translation ·

Explanation

The meaning in a few plain lines

Wọn beere lọwọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nipa iṣẹ ti o maa jẹ okunfa fun wiwọnu alujanna tabi nipa eyi ti Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ si julọ? Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ fun olubeere pe: Dunni mọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ iforikanlẹ nibi irun, o ko nii forikanlẹ fun Ọlọhun ni iforikanlẹ kan afi ki O fi gbe ẹ ga nípò, ki O si fi i ṣe aforijin fun ẹ.

Source
Muslim gba a wa
Download image

Saved at original quality