Fik'hu ati ìpìlẹ̀ rẹ
Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe:
Available in 60 languages
«Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: “Irun ọkunrin kan pẹ̀lú janmọọn ju irun rẹ nile lọ ati Irun rẹ ni ọja lọ pẹlu ipò ogún lé ní nǹkan kan. nitori pe ti ẹnìkan ninu wọn ba ṣe aluwala daadaa, lẹ́yìn naa o wa lọ sí mọ́sálásí, ko si nkankan ti o gbe e dide ayafi irun, ko si gbero nǹkan kan ayafi irun, nitori naa ko nii gbe ẹsẹ kan àyàfi ki Ọlọhun fi ṣe agbega fun un, ati ki O fi pa asiṣe rẹ rẹ́, titi ti yio fi wọ masalasi. Ti o ba ti wa wọ mọ́sálásí, o ti wa lori irun lópin igba ti o ba jẹ pe irun ni o n da a dúró, àwọn Malaika si ma maa ṣe adura fun ẹni kọọkan ninu yin ni iwọn igba ti o ba ṣi wa lori ijokoo ti o ti kirun, wọn maa sọ pe: Ọlọhun, ṣãnu fun un, Ọlọrun, dari jin in, Ọlọrun, gba ironupiwada rẹ, ni iwọn igba ti ko ba ti ṣe ipalara nibẹ, ti ko si ṣe ẹgbin nibẹ".»Meaning translation ·
Saved at original quality








