Hadith for the World
Tap the image to view it full size
Kuraani Alapọn-ọnle ati àwọn imọ rẹ

Lati ọdọ Abdullāh ọmọ Mas‘ūd – ki Ọlọhun yọnu si i – o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pe:

Available in 65 languages
«Lati ọdọ Abdullāh ọmọ Mas‘ūd – ki Ọlọhun yọnu si i – o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pe: «Ẹni ti o ba ka harafi kan ninu tira Ọlọhun, o maa fi gba ẹsan daada kan, ati pe ẹsan kan yio maa ni ilọpo mẹwaa iru rẹ, mi o sọ wipe “alif lām mīm” harafi kan ni o, amọ alifu harafi kan ni, lāmu naa harafi kan ni, mīmu naa harafi kan ni».»

Meaning translation ·

Explanation

The meaning in a few plain lines

Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ wípé dajudaju gbogbo Musulumi kọọkan ti o ba n ka harafi kan ninu tira Ọlọhun ni ẹsan kọọkan a máa bẹ fun un, ti wọn yio si ṣe adipele ẹsan naa fun un ni ilọpo mẹwaa iru rẹ. Lẹyin naa ni o wa ṣalaye pẹlu gbolohun rẹ ti o sọ pe: (Mi o sọ wipe “alif lām mīm” harafi kan ni o, amọ alif harafi kan ni, lām naa harafi kan ni, mīm naa harafi kan ni): Nítorí naa yio jẹ harafi mẹta ti o ko ẹsan ọgbọn sinu.

Source
Tirmiziy ni o gba a wa
Download image

Saved at original quality