Hadith for the World
Tap the image to view it full size
Adisọkan

Lati ọdọ Aishah- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe:

Available in 71 languages
«Lati ọdọ Aishah- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo sọ pé: Irẹ Òjíṣẹ́ Ọlọhun, Ibnu Jud’aan maa n da ibi pọ ni asiko ki Isilaamu to de, o si maa n fun awọn alaini ni oúnjẹ, njẹ ìyẹn maa ṣe e ni anfaani? O sọ pe: “Ko lee ṣe e ni anfaani, nitori pe ko fi ọjọ kan sọ pé: Irẹ Oluwa mi, fori awọn àṣìṣe mi jin mi ni ọjọ ẹsan".»

Meaning translation ·

Explanation

The meaning in a few plain lines

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ nipa Abdullahi Bn Jud’aan, o si wa ninu awọn aṣiwaju Kuraiṣi ṣíwájú Isilaamu, Ninu awọn iṣẹ daadaa rẹ ni pé: O maa n da awọn ẹbi pọ, o si maa n ṣe daadaa si wọn, o si maa n fun alaini ni oúnjẹ, ati eyi ti o yàtọ̀ si wọn ninu awọn iwa ọlọla ti Isilaamu ṣe wa lojukokoro lori ṣíṣe wọn, ati pe awọn iṣẹ yii ko lee ṣe e ni anfaani ni ọjọ igbedide rẹ; ìyẹn rí bẹ́ẹ̀ fun okunfa ṣíṣe aigbagbọ rẹ ninu Ọlọhun, ati pe ko fi ọjọ kan sọ pé: Irẹ Oluwa mi, forí awọn àṣìṣe mi jin mi ni ọjọ ẹsan.

Source
Muslim gba a wa
Download image

Saved at original quality