Hadith for the World
Tap the image to view it full size
Adisọkan

Lati ọdọ Uthman ọmọ Abul 'Aas- ki Ọlọhun yọnu si i-:

Available in 63 languages
«Lati ọdọ Uthman ọmọ Abul 'Aas- ki Ọlọhun yọnu si i-: Dajudaju o wa ba Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, dajudaju Shaitan ti wa laaarin mi ati irun mi ati kika mi, ti o n da a ru mọ mi loju, ni ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Iyẹn ni Shaitan kan ti wọn n pe ni Khinzab, ti o ba ti fura mọ ọn, ki o wa iṣọra pẹlu Ọlọhun kuro lọdọ rẹ, fẹ atẹgun si ẹgbẹ osi rẹ lẹẹmẹta", o sọ pe: Mo wa ṣe bẹẹ ni Ọlọhun ba mu u kuro lọdọ mi.»

Meaning translation ·

Explanation

The meaning in a few plain lines

Uthman ọmọ Abul 'Aas- ki Ọlọhun yọnu si i- wa ba Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o wa sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, dajudaju Shaitan kọdi laaarin mi ati laaarin irun mi, ti o kọ ipaya fun mi nibẹ, ti o da kika mi ru ti o si ko iyemeji ba mi nibẹ, Ni ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ba sọ fun un pe: Ìyẹn ni Shaitan ti wọn n pe ni Khinzab, ti o ba ri eyi ti o si fura mọ ọn, dirọ mọ Ọlọhun, ki o si wa iṣọra pẹlu Ọlọhun kuro lọdọ rẹ, ki o si fẹ atẹgun si ẹgbẹ osi rẹ pẹlu itọ diẹ lẹẹmẹta, Uthman sọ pe: Mo ṣe nnkan ti Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pa mi láṣẹ pe ki n ṣe, ni Ọlọhun si mu u kuro lọdọ mi.

Source
Muslim gba a wa
Download image

Saved at original quality