Hadith for the World
Awọn iwa ọlọla

Awọn ọla ti n bẹ fun iranti

10 hadiths

10 hadiths

Lati ọdọ Abu Dardaa- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Ṣé ki n fun yin ni iro nipa eyi ti o daa julọ ninu awọn iṣẹ yín, ati eyi ti o mọ julọ ninu rẹ lọdọ Oluwa yin, ati eyi ti o ga julọ ninu rẹ ninu awọn ipo yin ti o si loore julọ fun yin ju nina wura ati fadaka lọ, ti o si loore julọ fun yin ju ki ẹ pade ọta yin ki ẹ si ge awọn ọrun wọn ki wọn si ge ọrun yin lọ? Wọn sọ pé: Bẹẹni. O sọ pe: "Iranti Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-".Tirmiziy ati Ibnu Maajah ati Ahmad ni wọ́n gba a wa
Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n rin loju ọna Makkah, ni o ba kọjá nibi oke kan ti wọn n pe e ni Jumdaan, o sọ pe: "Ẹ maa rin lọ, Jumdaan nìyí, àwọn MUFARRIDUUN ti ṣíwájú" wọn sọ pe: Awọn wo ni MUFARRIDUUN irẹ ojiṣẹ Ọlọhun? O sọ pe: Awọn ni àwọn oluranti Ọlọhun lọkunrin lọpọlọpọ ati awọn oluranti Ọlọhun lobinrin".Muslim gba a wa
عن الْأَغَرِّ رضي الله عنه، وَكَانَ مِنْ أَصْحَابِ النَّبِيِّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ، قَالَ: قَالَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ: «يَا أَيُّهَا النَّاسُ تُوبُوا إِلَى اللهِ، فَإِنِّي أَتُوبُ فِي الْيَوْمِ إِلَيْهِ مِائَةَ مَرَّةٍ».رواه مسلم
Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i-: Lati ọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, ninu nǹkan ti o gba wa lati ọdọ Olúwa rẹ tí Ó lágbára ti O gbọnngbọn, O sọ pe: “Ẹru mi da ẹṣẹ kan, o wa sọ pé: Irẹ Ọlọhun, fi orí ẹṣẹ mi jin mi, Ọlọhun Àlekè-ọla wa sọ pé: Ẹrú Mi da ẹṣẹ kan, o si mọ pe oun ni Olúwa kan ti maa n ṣe àforíjìn ẹṣẹ, ti O si maa n fi iya ẹṣẹ jẹ eeyan, lẹyin naa o tun ṣẹri pada si idi ẹṣẹ, o wa tun sọ pé: Irẹ Oluwa mi, fi ori ẹṣẹ mi jin mi, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga tun sọ pé: Ẹrú Mi da ẹṣẹ kan, o si mọ pe oun ni Olúwa kan ti maa n ṣe àforíjìn ẹṣẹ, ti O si maa n fi iya ẹṣẹ jẹ eeyan, lẹyin naa o tun ṣẹri pada si idi ẹṣẹ, o wa tun sọ pé: Irẹ Oluwa mi, fi ori ẹṣẹ mi jin mi, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga tun sọ pé: Ẹrú Mi da ẹṣẹ kan, o si mọ pe oun ni Olúwa kan ti maa n ṣe àforíjìn ẹṣẹ, ti O si maa n fi iya ẹṣẹ jẹ eeyan, maa ṣe ohun ti o ba fẹ́, mo ti fi ori jin ọ”.Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
عن أبي ذر الغفاري رضي الله عنه عن النبي صلى الله عليه وسلم قال: «ألاَ أُخْبِرُكَ بِأَحَبِّ الكَلاَمِ إِلَى اللهِ؟ إنَّ أَحَبَّ الكلام إِلى الله: سبحان اللهِ وبحمدِهِ».رواه مسلم
عن أبي هريرة رضي الله عنه مرفوعاً: «والذي نفسي بيده، لو لم تذنبوا، لذهب الله بكم، وجاء بقوم يُذْنِبُونَ، فيستغفرون اللهَ تعالى، فيغفر لهم».رواه مسلم
عن أبي سعيد الخدري رضي الله عنه قال: قال رسول الله صلى الله عليه وسلم : "الْبَاقِيَاتُ الصَّالِحَاتُ، لَا إلَهَ إلَّا اللَّهُ، وَسُبْحَانَ اللَّهِ، وَاَللَّهُ أَكْبَرُ، وَالْحَمْدُ لِلَّهِ، وَلَا حَوْلَ وَلَا قُوَّةَ إلَّا بِاَللَّهِ".رواه ابن حبان والحاكم، أما النسائي فرواه في الكبرى لكن من حديث أبي هريرة
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- pe ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ẹni ti o ba sọ pe: SUBHAANALLOOHI WA BIHAMDIHII, ni ìgbà ọgọ́rùn-ún ni ojúmọ́, wọn maa pa àwọn ẹṣẹ rẹ rẹ kódà ki o da gẹgẹ bii ìfòfó agbami odò”.Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Lati ọdọ Abdullāh ọmọ ‘Amru ọmọ al-‘Aas – ki Ọlọhun yọnu si i – dajudaju o gbọ ti Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – n sọ pe: «Ti ẹ ba ti gbọ oluperun ki ẹ yaa maa sọ gẹgẹ bi o ṣe n sọ, lẹyin naa ki ẹ wa ṣe asalaatu fun mi, torí pé dajudaju ẹni ti o ba ṣe asalaatu kan fun mi Ọlọhun a fi ṣe mewaa fun un, lẹyin naa ki ẹ beere al-Wasiilah fun mi lọdọ Ọlọhun, ati pe dajudaju oun ni ipo kan ninu al-jannah, ti ko si lẹtọọ ayaafi fun ẹru kan ninu awọn ẹru Ọlọhun, mo si fẹ ki o jẹ emi, nitori naa ẹni ti o ba beere al-Wasiilah fun mi iṣipẹ ti di ẹtọ fun un».Muslim gba a wa
Lati ọdọ Uthman ọmọ Abul 'Aas- ki Ọlọhun yọnu si i-: Dajudaju o wa ba Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, dajudaju Shaitan ti wa laaarin mi ati irun mi ati kika mi, ti o n da a ru mọ mi loju, ni ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Iyẹn ni Shaitan kan ti wọn n pe ni Khinzab, ti o ba ti fura mọ ọn, ki o wa iṣọra pẹlu Ọlọhun kuro lọdọ rẹ, fẹ atẹgun si ẹgbẹ osi rẹ lẹẹmẹta", o sọ pe: Mo wa ṣe bẹẹ ni Ọlọhun ba mu u kuro lọdọ mi.Muslim gba a wa