Hadith for the World
Awọn iwa ọlọla

Awọn ọla ti n bẹ fun mimu Ọlọhun ni ọkan ṣoṣo

4 hadiths

4 hadiths

Lati ọdọ Abu Sa'eed Al-Khudriy ati lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: "Nnkan kan ko nii ṣẹlẹ̀ si Musulumi ninu wahala ati aisan ati ironu ati ibanujẹ ati suta ati ironu ati ki ẹgun gun un afi ki Ọlọhun ba a fi pa awọn aṣiṣe rẹ rẹ".Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Láti ọ̀dọ̀ Anas ọmọ Maalik- ki Ọlọhun yọnu si i- pe: Mu’aadh wa lẹ́yìn Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lori nnkan ọgun, o sọ pe: “Irẹ Mu’aadh ọmọ Jabal”, o sọ pe: Mo n da ẹ lohun irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, mo si n wa oriire fun dida ẹ lóhùn, o tun sọ pe: “Irẹ Mu’aadh”, o sọ pe: Mo n da ẹ lohun irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, mo si n wa oriire fun dida ẹ lóhùn, lẹẹmẹta, o sọ pe: “Ko si ẹni kankan ti o n jẹrii pe ko si ẹni ti ijọsin tọ si lododo afi Allahu, ati pe Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun ni lododo lati inu ọkan rẹ, afi ki Ọlọhun ṣe ina leewọ fun un”, o sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, njẹ mi ko nii maa sọ ọ fun awọn eniyan ki wọn le dunnu? O sọ pe: “Ti o ba ri bẹẹ wọn maa gbara le e”. Ni Mu’aadh wá sọ ọ́ nigba ti o fẹ ku ki o ma baa kó sínú ẹṣẹ.Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Lati ọdọ Mu’aadh- ki Ọlọhun yọnu si i-, o sọ pe: Mo wa lẹyin Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lori kẹtẹkẹtẹ kan ti wọn n pe ni ‘Ufair, o sọ pe: “Irẹ Mu’aadh, njẹ o mọ iwọ Ọlọhun lori awọn ẹrusin Rẹ, ati nnkan ti o jẹ iwọ àwọn ẹrusin lori Ọlọhun?”, mo sọ pe: Ọlọhun ati Ojiṣẹ Rẹ ni wọn ni imọ julọ, o sọ pe: “Dajudaju iwọ Ọlọhun lori awọn ẹrusin ni ki wọn maa jọsin fun Un ki wọn si ma da nnkan pọ mọ Ọn ninu ẹbọ, iwọ àwọn ẹrusin lori Ọlọhun ni ki O ma fi iya jẹ ẹni ti ko ba da nnkan pọ mọ Ọn ninu ẹbọ”, mo sọ pe: Irẹ Òjíṣẹ́ Ọlọhun, ṣe ki n maa fun awọn eniyan ni iro idunnu nipa rẹ? O sọ pe: “Rara, ma fun wọn ni iro ìdùnnú, ki wọn ma baa gbára lé e”.Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Lati ọdọ Jabir- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Arakunrin kan wa ba Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: Irẹ Òjíṣẹ́ Ọlọhun, ki ni nnkan meji naa ti wọn maa n sọ nǹkan di dandan? O sọ pe: “Ẹni ti o ba ku ti ko da ẹbọ kankan pọ mọ Ọlọhun yoo wọ alujanna, ẹni ti o ba si ku ti o da ẹbọ pọ mọ Ọlọhun yoo wọ ina".Muslim gba a wa