Hadith for the World
Imọ agbọye ẹsin nípa awọn iwa

Awọn iwa ẹyin

35 hadiths

35 hadiths

Láti ọ̀dọ̀ Sahd ọmọ Abu Waqqaas- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo gbọ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé: “Dájúdájú Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ si ẹrú ti o jẹ olupaya ọlọ́rọ̀ ti o pamọ́”.Muslim gba a wa
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Mumini ti o pe jù ni igbagbọ ni ẹni tí ìwà rẹ dara ju, ẹni tí ó loore ju ninu yin ni ẹni tí o dara ju fun awọn obinrin wọn”.Abu Daud ati Tirmiziy ati Ahmad ni wọ́n gba a wa
Láti ọ̀dọ̀ Aishah- ki Ọlọhun yọnu si i- ìyàwó Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- láti ọ̀dọ̀ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: “Dájúdájú ẹ̀lẹ̀ ko nii wa ninu nǹkan ayafi ki o ko ọ̀ṣọ́ ba a, wọn ko si nii yọ ọ kuro ninu nǹkan ayafi ki o ko àléébù ba a”.Muslim gba a wa
Láti ọ̀dọ̀ Aishah- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo gbọ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe: “Dájúdájú pẹ̀lú iwa dáadáa, mumini maa de ipo aláàwẹ̀ ti n dide fun ìjọsìn ni oru”.Abu Daud ati Ahmad ni wọ́n gba a wa
Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Amr- ki Ọlọhun yọnu si àwọn mejeeji- o sọ pe: Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kii se ọlọ́rọ̀ burúkú, kii sii mọ̀ọ́mọ̀ sọ ọrọ burúkú, o maa n sọ pe: “Dájúdájú ninu awọn ti wọn loore ju ninu yin ni àwọn tí ìwà wọn dára julọ”.Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Lati ọdọ Anas ọmọ Maalik- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: “Ẹ maa ṣe idẹkun fun awọn èèyàn, ẹ ma ṣe fi ara ni wọn, ẹ maa fun awọn èèyàn ni ìró ìdùnnú, ẹ ma ṣe lé wọn sá”.Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
عَنْ أَبِي مُوسَى الأَشْعَرِيِّ رَضِيَ اللَّهُ عَنْهُ عَنِ النَّبِيِّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ: «أَطْعِمُوا الجَائِعَ، وَعُودُوا المَرِيضَ، وَفُكُّوا العَانِيَ».رواه البخاري
Lati ọdọ Abdullāh ọmọ ‘Amri – ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji – dajudaju Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pe: «Awọn olùṣe ikẹ, Ọlọhun Ajọkẹ aye maa kẹ wọn, ẹ maa kẹ awọn ti n bẹ lori ilẹ, Ọba ti n bẹ ni sanmọ a kẹ ẹyin naa».Abu Daud ati Tirmiziy ati Ahmad ni wọ́n gba a wa
Lati ọdọ Abdullāh ọmọ Amru - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji - lati ọdọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o sọ pe: «Musulumi ni ẹni ti awọn musulumi la nibi ahọn rẹ ati ọwọ rẹ, ati pe Al-muhaajiru ni ẹni ti o yan nkan ti Ọlọhun kọ lodi».Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
عَن أَبي هُرَيْرَةَ، قَالَ: قَامَ رَسُولُ اللَّهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ فِي صَلاَةٍ وَقُمْنَا مَعَهُ، فَقَالَ أَعْرَابِيٌّ وَهُوَ فِي الصَّلاَةِ: اللَّهُمَّ ارْحَمْنِي وَمُحَمَّدًا، وَلاَ تَرْحَمْ مَعَنَا أَحَدًا. فَلَمَّا سَلَّمَ النَّبِيُّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ لِلْأَعْرَابِيِّ: «لَقَدْ حَجَّرْتَ وَاسِعًا» يُرِيدُ رَحْمَةَ اللهِ.رواه البخاري
عَنْ أَنَسِ بْنِ مَالِكٍ رَضِيَ اللَّهُ عَنْهُ قَالَ: سَمِعْتُ النَّبِيَّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ يَقُولُ: «إِنَّ اللَّهَ قَالَ: إِذَا ابْتَلَيْتُ عَبْدِي بِحَبِيبَتَيْهِ فَصَبَرَ، عَوَّضْتُهُ مِنْهُمَا الجَنَّةَ» يُرِيدُ: عَيْنَيْهِ.رواه البخاري