Hadith for the World
Agbọye awọn adua ati awọn ir

Awọn iranti àárọ̀ ati irọlẹ

4 hadiths

4 hadiths

عن عبد الله بن مسعود رضي الله عنه قال: كان نبي الله صلى الله عليه وسلم إذا أمسى قال: «أمسينا وأمسى الملك لله، والحمد لله، لا إله إلا الله وحده لا شريك له» قال الراوي: أَرَاهُ قال فِيهِنَّ: «له الملك وله الحمد وهو على كل شيء قدير، ربِّ أسألك خير ما في هذه الليلة وخير ما بعدها، وأعوذ بك من شر ما في هذه الليلة وشر ما بعدها، رب أعوذ بك من الكسل، وسُوءِ الكِبَرِ، رب أعوذ بك من عذاب في النار، وعذاب في القبر»، وإذا أصبح قال ذلك أيضا «أصبحنا وأصبح الملك لله».رواه مسلم
Lati ọdọ Shaddad bin Aws, ki Ọlọhun yọnu si i, lati ọdọ anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a –: “Olori iwaforijin ni ki o sọ pe: Allahummọ anta Rọbbii laa ilaaha illaa anta, khalaqtanii, wa anaa abduka wa anaa alaa ahdika wawahdika mastatahtu, auuzu bika min sharri maa sanahtu, abuuhu laka binihmatika alayya, wa abuuhu bizambii, fagfir lii, fa innahuu laa yagfiruz zunuuba illaa anta", o sọ pe: Ẹni ti o ba sọ ọ ni aarọ ti o si ni amọdaju pẹlu ẹ, ti o wa kú, ni ọjọ naa ki o to di irọlẹ, o maa wa ninu awọn ọmọ alujanna, ẹni tí ó bá sọ ọ ni alẹ ti o si ni amọdaju pẹ̀lú ẹ, ti o wa kú ki ilẹ o to mọ́, o maa wa ninu awọn ọmọ alujanna".Bukhaariy gba a wa
Lati ọdọ Abdullāh ọmọ Khubayb - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: A jade ni alẹ ọjọ kan ti ojo n rọ ti o si ṣokunkun gidigidi, ti a n wa Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a; lati kirun fun wa, o sọ pe: Ni a ba ri i, ni o wa sọ pe: «Sọ», mi o si sọ nkankan, lẹyin naa o sọ pe: «Sọ», mi ò si sọ nkankan, o sọ pe: «Sọ», ni mo ba sọ pe: Kini maa sọ? O sọ pe: «{Qul Uwal Laahu ahad} ati Al-mu‘awwidhatayn (Falaqi ati Naasi) nigba ti o ba di irọlẹ ati ti o ba di afẹmọjumọ ni igba mẹta, yio to ọ nibi gbogbo nkan».Abu Daud ati Tirmiziy ati Nasaa'iy ni wọn gba a wa
Lati ọdọ Abu Mas‘ūd – ki Ọlọhun yọnu si i– o sọ pe: Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pe: «Ẹni ti o ba ka aayah meji ti o gbẹyin Sūratul Bakọra ni oru kan, wọn ti to fún un».Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni