Hadith for the World
Awọn ọrọ ti maa n rọ emi ati awọn isiti

Aleebu awọn ẹṣẹ

6 hadiths

6 hadiths

Lati ọdọ Abu Bakra - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: “Njẹ emi ko wa ni fun yin ni iro nipa awọn ti o tobi ju ninu awọn ẹṣẹ ńlá bi?” O sọ bẹẹ ni igba mẹ́ta, wọn sọ pe: A fẹ bẹẹ irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, o sọ pe: “Mimu orogun pẹ̀lú Ọlọhun ati yiyapa aṣẹ awọn obi mejeeji”, o wa jokoo, o si jẹ ẹni ti o rọgbọku tẹlẹ, ni o wa sọ pe: “Ẹ gbọ o, ati ọrọ eke”, o sọ pe: Ko wa yẹ ni ẹni ti n wi i ni awitunwi titi ti a fi sọ pe: Iba tiẹ si dakẹ.Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Amru ọmọ ‘Aas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: “Awọn ẹṣẹ nlanla ni: Mimu orogun pẹlu Ọlọhun, ṣiṣẹ baba ati ìyá, pipa ẹmi, ati bibura lori irọ”.Bukhaariy gba a wa
Lati ọdọ Abu Musa- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: Dajudaju àpèjúwe olubajokoo rere ati olubajokoo burúkú da gẹgẹ bi ẹni ti o gbe almisiki ati eni ti o n fẹ ina alagbẹdẹ ẹni ti o gbe almisiki: Ninu ki o fun ọ nínú ẹ, tabi ninu ki o ra ọjà lọwọ rẹ, tabi ki o ri oorun ti o daa latara rẹ, ati pe ẹni ti o n fẹ iná alagbẹdẹ: Ninu ki o jo aṣọ rẹ, tabi ki o ri oorun ti o buru".Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Lati ọdọ Abu Hurairah, ki Ọlọhun yọnu si i, o gba a wa lati ọdọ Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, o sọ pe: “Ẹ yẹra fún awọn nkan meje tí n pani run” Wọ́n sọ pé: Irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun, kí ni awọn nkan naa? Ó ní: “Ṣíṣe ẹbọ pẹ̀lú Ọlọhun, pípidán, pípa eniyan tí Ọlọhun ṣe ní eewọ, àyàfi pẹlu ẹ̀tọ́, jíjẹ owó èlé, jíjẹ owó ọmọ òrukàn, sísálọ ní ọjọ́ ogun ẹsin, ati jíju òkò ṣina mọ́ awọn obinrin abilékọ, onígbàgbọ́ ododo, àwọn tí sìná kò sí lórí ọkàn wọn”.Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Mo gbọ ti ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n sọ pe: «Gbogbo ijọ mi ni wọn maa ṣọ kuro nibi aburu ayaafi awọn alaṣehan, ati pe dajudaju ninu aṣehan ni ki ọmọnìyàn o ṣe iṣẹ kan ni oru, lẹyin naa ki o wa ji ti Ọlọhun si ti bo aṣiri rẹ, ki o wa sọ pe: Irẹ lagbaja, mo ṣe nkan bayii bayii ni alẹ ana, ti Ọlọhun si ti bo aṣiri rẹ ni alẹ, yio waa ji lati ṣi gaga aṣiri bibo Ọlọhun kuro».Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
عن أبي هريرة عن النبي صلى الله عليه وسلم قال: «لعن الله السارق، يسرق البَيْضَةَ فَتُقْطَعُ يده، ويسرِقُ الحَبْلَ فَتُقْطَعُ يَدُهُ».متفق عليه