Hadith for the World
Topic

Adisọkan

135 hadiths

135 hadiths

عن أبي هريرة رضي الله عنه مرفوعًا: «إِنَّ الله تَعَالى يَقُول يَوْمَ القِيَامَة: أَيْنَ المُتَحَابُّونَ بِجَلاَلِي؟ اليَوم أُظِلُّهُم فِي ظِلِّي يَوْمَ لاَ ظِلَّ إِلاَّ ظِلِّي».رواه مسلم
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Ẹni ti o ba pepe lọ si ibi imọna, iru awọn ẹsan ti o n bẹ fun ẹni ti o ba tẹle e, maa wa fun un ninu ẹsan, ti ìyẹn ko nii din nnkan kan ku ninu awọn ẹsan wọn, ati pe ẹni ti o ba pepe lọ si ibi anu, iru awọn ẹṣẹ ti o n bẹ fun ẹni ti o ba tẹle e, maa wa fun un ninu ẹṣẹ, ti ìyẹn ko nii din nnkan kan ku ninu awọn ẹṣẹ wọn".Muslim gba a wa
Lati ọdọ Mahmud ọmọ Labiid- ki Ọlọhun yọnu si i- dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Dajudaju nnkan ti mo n bẹru julọ nipa yin ni ẹbọ kekere" wọn sọ pe: Ki ni ẹbọ kekere irẹ ojiṣẹ Ọlọhun? O sọ pe: "Ṣekarimi ni, Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- maa sọ fun wọn ni ọjọ igbedide ti wọn ba ti san awọn eniyan lẹsan pẹlu awọn iṣẹ wọn pé: Ẹ lọ ba awọn ti ẹ maa n ṣe karimi fun ni aye, ki ẹ si wo boya ẹ maa ri ẹsan kankan lọdọ wọn?"Ahmad ni o gba a wa
Lati ọdọ Umar ọmọ Al-Khattab - ki Ọlọhun yọnu si i - ó sọ pé: Mo gbọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - tí ń ṣo pé: "Ẹ má ṣe yìn mi jù gẹgẹ bi awọn Kristẹni ṣe yin ọmọ Maria jù; ẹrú Ọlọhun ni ẹmi n ṣe, nitori naa, ẹ wi pe: Ẹru Ọlọhun ati Ojiṣẹ Rẹ̀".Bukhaariy gba a wa
Lati ọdọ Abu Hurairah - ki Ọlọhun yọnu si i - dajudaju ó sọ pé: Wọ́n sọ pé: Iwọ Ojiṣẹ Ọlọhun, ta ni yoo ṣoriire jù ninu awọn eniyan pẹlu ìṣìpẹ̀ rẹ ni ọjọ Igbende? Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - dahun bayii wi pe: "Irẹ Abu Hurairah, mo ti rò naa pé ko si ẹnikan ti yoo bi mi leere nipa hadiisi yii saaju rẹ, nigba ti mo ti ri itaraṣaṣa rẹ si imọ hadiisi, Ẹnití ó maa ṣoriire jù pẹlu ìṣìpẹ̀ mi ní ọjọ Igbende, oun ni ẹniti ó bá sọ pé ko si ọlọhun miran ayafi Ọlọhun Allah, tí ó ṣo bẹẹ pẹlu ododo lati inu ọkàn rẹ̀".Bukhaariy gba a wa
عن عبد الله بن عمرو بن العاص - رضي الله عنه- مرفوعاً: "مَن ردته الطِّيَرَة عن حاجته فقد أشرك، قالوا: فما كفارة ذلك؟ قال: أن تقول: اللهم لا خير إلا خيرك، ولا طَيْرَ إِلَّا طَيْرُكَ ولا إله غيرك".رواه أحمد
Lati ọdọ ‘Ubadah - ki Ọlọhun yọnu si i - lati ọdọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o sọ pe: «Ẹni ti o ba jẹrii pe ko si ẹni ti ijọsin ododo tọ si ayaafi Allāhu ni ọkan soso ti ko si akẹgbẹ fun Un, ati pe dajudaju Muhammad ẹrusin Rẹ ati ojiṣẹ Rẹ ni, ati pe Isa ẹrusin Ọlọhun ni ojiṣẹ Rẹ si tun ni ati pe ọ̀rọ̀ Rẹ̀ (kun fayakūn) tí Ó sọ ránṣẹ́ sí Mọryam l’Ó sì fi ṣẹ̀dá rẹ̀. Ẹ̀mí kan (tí Allāhu ṣẹ̀dá) láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni, ati pe al-jannah ododo ni, ina ododo ni, Ọlọhun a mu u wọ al-jannah lori èyíkéyìí iṣẹ ti o ba wa lori rẹ»Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Mas'ud- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ ọrọ kan, emi naa sọ omiran, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Ẹni ti o ba ku ti o si n pe akẹgbẹ kan ti o yàtọ̀ si Ọlọhun, o maa wọ ina" emi naa sọ pe: Ẹni ti o ba ku, ti ko si kii n pe akẹgbẹ kan mọ Ọlọhun, o maa wọ alujanna.Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
عن أبي هريرة رضي الله عنه مرفوعًا: «صلاة الرجل في جماعة تَضعُفُ على صلاته في بيته وفِي سُوقِه خمسا وعشرين ضِعفًا، وذلك: أَنَّه إِذَا تَوَضَّأ، فَأَحسَن الوُضُوء، ثمَّ خرج إلى المسجد لاَ يُخرِجُهُ إلاَّ الصلاة؛ لَم يَخْطُ خُطوَةً إِلاَّ رُفِعَت له بِها درجة، وَحُطَّ عَنهُ بها خطيئة، فإذا صلَّى لم تزل الملائكة تُصَلِّي عليه، ما دام في مُصَلاَّه: اللهُمَّ صَلِّ عليه، اللهم اغفِر له، اللهم ارْحَمه، ولا يزال في صلاة ما انتظر الصلاة».متفق عليه
Láti ọdọ Jaabir ọmọ Abdullahi kí Ọlọhun yọnu sí awan méjèjì, dájú dájú anọbi kí ikẹ Ọlọhun àti Ọlá Rẹ má bà sọ pé: « wan tí fún mí ni nkán márùn tí wan kọ fún ẹni kánkan síwájú mí : wan fí ọwọ àti igbakẹ kankan mú aranse ba míOhun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
عن معاذ بن جبل رضي الله عنه عن رسول الله صلى الله عليه وسلم أنه قال: «قَالَ اللهُ -عَزَّ وجَلَّ-: المُتَحَابُّون فِي جَلاَلِي، لَهُم مَنَابِرُ مِن نُورٍ يَغْبِطُهُم النَبِيُّونَ والشُهَدَاء».رواه الترمذي وأحمد
عن أبي هريرة رضي الله عنه أن رسول الله صلى الله عليه وسلم قال: «إنَّ في الجنَّة مائةَ دَرَجَة أعَدَّهَا الله للمُجاهِدين في سَبِيل الله ما بَيْنَ الدَّرَجَتَيْنِ كما بين السماء والأرض».رواه البخاري
Lati ọdọ Abu Hurayrah - kí Ọlọhun yọnu si i - o sọ bayi pe: Òjíṣẹ Ọlọhun (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) sọ pé: Allah Ọlọhun ti O gbọngbọn ti O ga jùlọ sọ pé: Emi wà pẹlu aba ti ẹru mi dá sí mi, Emi si wà pẹlu rẹ nigbati o ba rántí Mi , ti o ba rántí mi ninu ẹmi rẹ Emi naa yóò rántí rẹ ninu ẹmi Mi, ti o ba rántí mi làárìn awọn ìjọ Emi naa yóò rántí rẹ láárín awọn ti wọn lóore jù ìjọ tiẹ lọ, ti o bá sun mọ mi ni iwọn àlàfo ni na ọmọnika tán Emi yóò sún mọ ni iwọn ni na igunpá, ti o bá sun mọ Mi ni iwọn gigun apá Emi yóò sún mọ ni iwọn gigun ni na apa méjèejì lẹẹkan naa, ti o bá wá bá mi ni eniti nrin, Emi yóò wá bá ní Ẹni ti nyara.Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Eyi ti o loore julọ ninu ọjọ ti oorun yọ nibẹ ni ọjọ Jímọ̀, ninu rẹ ni wọn ṣẹda Aadam, ninu rẹ ni wọn mu u wọ alujanna, ninu rẹ ni wọn mu u jade kúrò nibẹ, ọjọ́ igbende ko lee to afi ni ọjọ Jimọ".Muslim gba a wa
عن أبي هريرة رضي الله عنه عن النبي صلى الله عليه وسلم قال: «كان داود -عليه السلام- لا يأكلُ إلا من عمل يده». وعن المقدام بن معد يكرب رضي الله عنه عن النبي صلى الله عليه وسلم قال: «ما أكل أحد طعاما قط خيرا من أن يأكل من عمل يده، وإن نبي الله داود صلى الله عليه وسلم كان يأكل من عمل يده».حديث أبي هريرة رضي الله عنه: رواه البخاري. حديث المقداد رضي الله عنه: رواه البخاري
عن ابن مسعود رضي الله عنه قال: قال رسول الله صلى الله عليه وسلم : «من أصابته فَاقَة فأنْزَلها بالناس لم تُسَدَّ فَاقَتُهُ، ومن أنْزَلها بالله، فَيُوشِكُ الله له بِرزق عاجل أو آجل».رواه أبو داود والترمذي وأحمد
Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: “Ẹni ti o ba lọ onigbese lára, tabi ti o ba a din in ku tabi ki o ni ki o ma san an mọ́, Ọlọhun maa fi i sábẹ́ ibòji Ìtẹ́-ọlá Rẹ̀ ni Ọjọ́ Àjíǹde, ni ọjọ́ ti ko nii si ibòji kankan àyàfi ibòji Rẹ̀”.Tirmiziy ati Ahmad ni wọ́n gba a wa
Lati ọdọ ọmọ Abbas kí Ọlọhun yọnu sí awan méjèjì dájú daju òjíṣẹ Ọlọhun kí ikẹ àti ọlá rẹ máa ba sọ pé: « Dájú dájú Ọlọhun ti se amojukuro aṣiṣe àti ìgba gbé fún mi nípa awan ìjọ mí àti nkán tí wan ba jẹ wàn nípa láti ṣe ».رواه ابن ماجه والبيهقي وغيرهما
عن أبي هريرة رضي الله عنه قال: سمعت رسول الله صلى الله عليه وسلم يقول: «جَعَلَ اللهُ الرحمةَ مائة جُزْءٍ، فَأَمْسَكَ عِنْدَهُ تِسْعَةً وَتِسْعِينَ، وأَنْزَلَ في الأَرْضِ جُزْءًا وَاحِدًا، فَمِنْ ذَلِكَ الجُزْءِ يَتَرَاحَمُ الخَلَائِقُ، حتى تَرْفَعَ الدَّابَّةُ حَافِرَهَا عَنْ وَلَدِهَا خَشْيَةَ أَنْ تُصِيبَهُ». وفي رواية «إِنَّ للهِ تعالى مئةُ رحمةٍ، أَنْزَلَ منها رحمةً واحدةً بَيْنَ الجِنِّ والإنسِ والبَهَائِمِ والهَوَامِّ، فَبِهَا يَتَعَاطَفُونَ، وبها يَتَرَاحَمُونَ، وبِهَا تَعْطِفُ الوَحْشُ على وَلَدِهَا، وأَخَّرَ اللهُ تعالى تِسْعًا وتِسْعِينَ رحمةً يَرْحَمُ بِهَا عِبَادَهُ يومَ القِيَامَةِ». وعن سلمان الفارسي رضي الله عنه قال: قال رسول الله صلى الله عليه وسلم : «إِنَّ للهِ تعالى مئةُ رحمةٍ فمنها رحمةٌ يَتَرَاحَمُ بها الخَلْقُ بَيْنَهُمْ، وتِسْعٌ وتِسْعُونَ لِيَومِ القِيَامَةِ». وفي رواية: «إِنَّ اللهَ تَعَالَى خَلَقَ يَوْمَ خَلَقَ السَّمَاوَاتِ والأَرْضَ مئةَ رحمةٍ كُلُّ رحمةٍ طِبَاقَ مَا بَيْنَ السَّمَاءِ إلى الأَرْضِ، فَجَعَلَ منها في الأَرْضِ رَحْمَةً فبها تَعْطِفُ الوَالِدَةُ على وَلَدِهَا، والوَحْشُ والطَّيْرُ بَعْضُهَا عَلَى بَعْضٍ، فإذا كانَ يومُ القيامةِ أَكْمَلَهَا بِهَذِه الرحمةِ».حديث أبي هريرة -رضي الله عنه-: متفق عليه. حديث سلمان -رضي الله عنه-: رواه مسلم
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Dájúdájú Ọlọhun ko nii wo àwòrán yin ati dúkìá yin, ṣùgbọ́n O maa wo ọkàn yin ati iṣẹ yin”.Muslim gba a wa
Láti ọ̀dọ̀ Abu Dharr- ki Ọlọhun yọnu si i-: Láti ọ̀dọ̀ Anọbi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- ninu ohun ti o gba wa lati ọdọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- O sọ pe: “Ẹ̀yin ẹrusin Mi, Emi ṣe abosi ni eewọ fun ara Mi, Mo si ṣe e ni eewọ laarin yin, ẹ ma ṣe abosi si ara yin, ẹ̀yin ẹrú Mi, gbogbo yin ni ẹ sọnù, ayafi ẹni tí Mo ba ṣe imọna fun; nitori naa ẹ wa imọna lọ́dọ̀ Mi, Emi yoo si ṣe amọna yin, ẹyin ẹrú Mi, ebi n pa gbogbo yin ayafi ẹni ti mo ba bọ́; nitori náà, ẹ wá oúnjẹ lọ́dọ̀ Mi, èmi yóò sì bọ́ yín. Ẹ̀yin ẹrú Mi, gbogbo yin ni ẹ wa ni ihoho ayafi eni ti Mo ba da aṣọ bo; nitori naa ẹ wa dida aṣọ bo yin lọ́dọ̀ Mi, maa da aṣọ bo yín, ẹ̀yin ẹrú Mi, ẹ n da ẹṣẹ loru ati ni ọsan, Mo si maa n ṣe aforijin àwọn ẹṣẹ pata, ki ẹ yaa wa aforijin Mi, maa forí jin yin, ẹyin ẹrú Mi, ẹ ko le de ibi ìnira Mi débi pé ẹ maa ni Mi lara, ẹ ko si lee debi anfaani Mi debi pe ẹ maa ṣe mi ni anfaani. Ẹyin ẹrusin Mi, ti ẹni akọkọ yin ati ẹni ti o kẹhin ninu yin, eniyan yin ati awọn alujannu yin, tí wọ́n ba wa lori ọkàn arákùnrin kan ti o páyà Ọlọhun jù lọ ninu yin, iyẹn ko le nǹkan kan kun ninu ọla Mi. Ẹyin ẹrusin Mi, ti ẹni akọkọ yin ati ẹni ti o kẹhin ninu yin, eniyan yin ati awọn alujannu yin, tí wọ́n ba wa lori ọkàn arákùnrin kan ti o yapa Ọlọhun jù lọ ninu yin, iyẹn ko din nǹkan kan kù ninu ọla Mi. Ẹyin ẹrusin Mi, ti ẹni akọkọ yin ati ẹni ti o kẹhin ninu yin, eniyan yin ati awọn alujannu yin, tí wọ́n ba dúró lórí ilẹ̀ kan, ki wọn wa maa tọrọ lọ́wọ́ Mi, ki n wa maa fun èèyàn kọ̀ọ̀kan ni ohun ti n beere, ìyẹn ko din nǹkan kan ku ninu ohun ti n bẹ lọdọ Mi, àyàfi gẹgẹ bii ohun ti abẹrẹ maa dinku ti wọn ba ki i bọ inu omi òkun, ẹyin ẹrusin Mi, Mo n ṣe akọsilẹ iṣẹ yin fun yin, lẹyin naa Mo maa san ẹsan rẹ fun yin, ẹnikẹni ti o ba ri oore, ki o dúpẹ́ fun Ọlọhun, ẹni ti o ba si ri yatọ si iyẹn, ki o ma ṣe bu ẹnikan ayafi ara rẹ”.Muslim gba a wa
Lati ọdọ Ibnu Abbas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: “Mo wa lẹyin Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni ọjọ kan, o wa sọ pe: “Irẹ ọmọkunrin yii, emi yoo kọ ọ ni àwọn ọrọ kan pe: Máa ṣọ́ Ọlọhun, yoo si daabo bo ọ. Maa ṣọ Ọlọhun, iwọ yoo ri I ni iwaju rẹ. Ti o ba beere, beere lọwọ Ọlọhun, ati pe nígbà tí o ba wa iranlọwọ, wa iranlọwọ Ọlọhun. Mọ pe ti gbogbo ẹda ba pejọ lati ṣe nkan lati ṣe anfaani fun ọ, wọn ko nii ṣe àǹfààní kankan fun ọ rara ayafi pẹ̀lú nǹkan ti Ọlọhun ti kọ fun ọ. Ati pe ti wọn ba pejọ lati ṣe nkan lati ṣe ipalara fun ọ, wọn ko nii ṣe ipalara fun ọ rara ayafi pẹ̀lú nǹkan ti Allah ti kọ fun ọ. Wọn ti gbé àwọn ìkọ̀wé sókè, àwọn tákàdá si ti gbẹ.”Tirmiziy ni o gba a wa
عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رَضيَ اللهُ عنه أَنَّ رَسُولَ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ، قَالَ: «أَحَبُّ الْبِلَادِ إِلَى اللهِ مَسَاجِدُهَا، وَأَبْغَضُ الْبِلَادِ إِلَى اللهِ أَسْوَاقُهَا».رواه مسلم
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- pe ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Gbogbo ìjọ mi ni yoo wọ alujanna ayafi ẹni tí ó bá kọ̀”, wọn sọ pé: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, ta ni o maa kọ̀? O sọ pe: “Ẹni ti o ba tẹle àṣẹ mi yoo wọ alujanna, ẹni tí ó bá yapa àṣẹ mi ti kọ̀”.Bukhaariy gba a wa