Hadith for the World
Adisọkan

Àwọn orúkọ ati awọn ìdájọ́

22 hadiths

22 hadiths

Lati ọdọ Abu Musa Al-Ash’ariy- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: «Ẹni ti o ba kọ oju ija si wa pẹlu ohun ìjà, ko kii ṣe ara wa».Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: Ẹ yára si awọn iṣẹ daadaa siwaju ki awọn fitina kan ti yio da bii oru ti o ṣokunkun gan o to de, ti ọmọniyan o ji ni mumini ti yio si di alẹ ni keferi, tabi ki o di alẹ ni mumini ki o si ji ni keferi, ti yio ta ẹsin rẹ tori adun aye ti ko nii pẹ tan.Muslim gba a wa
عن أبي هريرة رضي الله عنه مرفوعاً: «الإيمانُ بِضْعٌ وَسَبْعُونَ أو بِضْعٌ وسِتُّونَ شُعْبَةً: فَأَفْضَلُهَا قَوْلُ: لا إله إلا الله، وَأَدْنَاهَا إِمَاطَةُ الأَذَى عَنِ الطَّرِيقِ، وَالحَيَاءُ شُعْبَةٌ مِنَ الإِيمَانِ».متفق عليه
Lati ọdọ Abu Hurairah, ki Ọlọhun yọnu si i, ó gba a wá lati ọdọ Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a: “Ọlọhun, má ṣe sọ saare mi di òrìṣà, Ọlọhun ti ṣẹbi lé awọn ijọ kan tí wọ́n sọ saare awọn Anabi wọn di mọṣalaṣi”.Ahmad ni o gba a wa
Lati ọdọ Abu Hurairah, ki Ọlọhun yọnu si i, o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, sọ pe: «Dajudaju irun ti o wuwo ju fun awọn munaafiki ni irun Ishai ati Asunbaa, ka ni wọn mọ nkan ti n bẹ ninu rẹ - ni ẹsan – ni, wọn o ba wa ki i koda ki o jẹ ni irakoro, ati pe mo ti wa gbero lati paṣẹ ki wọn o gbe irun duro, lẹyin naa ki n wa pa ẹnikan laṣẹ ki o ki i, lẹyin naa ki n wa gbera pẹlu awọn ọkunrin kan ti idi igi wa pẹlu wọn lọ si ọdọ awọn ijọ kan ti wọn o ki n wa ki irun ni masalaasi, ki n si sun ile wọn mọ wọn lori».Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Ẹni ti o ba pepe lọ si ibi imọna, iru awọn ẹsan ti o n bẹ fun ẹni ti o ba tẹle e, maa wa fun un ninu ẹsan, ti ìyẹn ko nii din nnkan kan ku ninu awọn ẹsan wọn, ati pe ẹni ti o ba pepe lọ si ibi anu, iru awọn ẹṣẹ ti o n bẹ fun ẹni ti o ba tẹle e, maa wa fun un ninu ẹṣẹ, ti ìyẹn ko nii din nnkan kan ku ninu awọn ẹṣẹ wọn".Muslim gba a wa
Lati ọdọ Mahmud ọmọ Labiid- ki Ọlọhun yọnu si i- dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Dajudaju nnkan ti mo n bẹru julọ nipa yin ni ẹbọ kekere" wọn sọ pe: Ki ni ẹbọ kekere irẹ ojiṣẹ Ọlọhun? O sọ pe: "Ṣekarimi ni, Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- maa sọ fun wọn ni ọjọ igbedide ti wọn ba ti san awọn eniyan lẹsan pẹlu awọn iṣẹ wọn pé: Ẹ lọ ba awọn ti ẹ maa n ṣe karimi fun ni aye, ki ẹ si wo boya ẹ maa ri ẹsan kankan lọdọ wọn?"Ahmad ni o gba a wa
عن عبد الله بن عمرو بن العاص - رضي الله عنه- مرفوعاً: "مَن ردته الطِّيَرَة عن حاجته فقد أشرك، قالوا: فما كفارة ذلك؟ قال: أن تقول: اللهم لا خير إلا خيرك، ولا طَيْرَ إِلَّا طَيْرُكَ ولا إله غيرك".رواه أحمد
Lati ọdọ An-Nu‘mān ọmọ Bashīr - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Apejuwe awọn Mumuni nibi nini ifẹ ara wọn ati kikẹ ara wọn ati nini aanu ara wọn da gẹgẹ bi apejuwe odidi ara, nigba ti orike kan ba n ke irora gbogbo ara yoku ni yio para pọ pẹlu rẹ nibi aisun ati igbona.Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
عَنْ عَبْدِ اللَّهِ بنِ مَسْعُودٍ رَضِيَ اللَّهُ عَنْهُ قَالَ: قَالَ النَّبِيُّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ: «لَيْسَ مِنَّا مَنْ لَطَمَ الخُدُودَ، وَشَقَّ الجُيُوبَ، وَدَعَا بِدَعْوَى الجَاهِلِيَّةِ».متفق عليه
Lati ọdọ àwọn kan ninu awọn ìyàwó Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lati ọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: “Ẹni ti o ba lọ ba yẹmiwo kan ti o wa bi i leere nipa nnkan kan, wọn ko nii gba irun rẹ fun ogoji ọjọ”.Muslim gba a wa
Lati ọdọ Abu Hurairah, ki Ọlọhun yọnu si i, o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, sọ pe: “Igbagbọ jẹ ipin aadọrin ati nnkankan- tabi ọgọta ati nnkankan-, eyi ti o ni ọla julọ nibẹ ni gbolohun Laa ilaaha illallohu, eyi ti o kere julọ nibẹ ni mimu suta kuro lọna, ati pe itiju jẹ ipin kan ninu igbagbọ”.Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
عَنْ بُرَيْدَةَ رضي الله عنه قَالَ: قَالَ رَسُولُ اللَّهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ: «مَنْ حَلَفَ بِالْأَمَانَةِ فَلَيْسَ مِنَّا».رواه أبو داود وأحمد
Lati ọdọ Abdullāh ọmọ Amru - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji - lati ọdọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o sọ pe: «Musulumi ni ẹni ti awọn musulumi la nibi ahọn rẹ ati ọwọ rẹ, ati pe Al-muhaajiru ni ẹni ti o yan nkan ti Ọlọhun kọ lodi».Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Lati ọdọ Abdullāh ọmọ Umar - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Wọn mọ Isilaamu pa lori nkan márùn-ún: Ijẹrii pe ko si ẹni ti ijọsin ododo tọ si ayaafi Allāhu, ati pe dajudaju Muhammad ẹru Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ ni, ati imaa gbe irun duro, ati imaa yọ zakah, ati imaa gbero ile Oluwa, ati gbigba aawẹ Ramadan».Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Lati ọdọ Abu Sa’eed Al-Khudri- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo gbọ ti Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o n sọ pe: "Ẹni ti o ba ri ibajẹ kan ninu yin, ki o yi i pada pẹlu ọwọ rẹ, ti ko ba ni ikapa ìyẹn, ki o yi i pada pẹlu ahọn rẹ, ti ko ba ni ikapa ìyẹn, ki o yi i pada pẹlu ọkan rẹ, ati pe ìyẹn ni o lẹ julọ ninu igbagbọ".Muslim gba a wa
Lati ọdọ Abu Maalik Al-Ash’ari- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Imọra ni idaji igbagbọ, ati pe sisọ gbolohun ALHAMDULILLAH maa n kun òṣùwọ̀n, ati pe sisọ gbolohun ALHAMDULILLAH ati gbolohun SUBHAANALLAH, mejeeji maa n kun- tabi o n kun- nnkan ti o n bẹ laaarin sanmọ ati ilẹ, ati pe irun jẹ imọlẹ, saara jẹ awijare, suuru jẹ imọlẹ, Kuraani maa jẹ ẹri fun ẹ tabi ki o tako ẹ, gbogbo eniyan yoo maa jáde lọ ní aarọ ni ẹni ti o n ta ẹmi ara rẹ, ninu ki o la a kúrò ninu iná, tabi ki o ko ìparun ba a”.Muslim gba a wa
Lati ọdọ Aishah- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo sọ pé: Irẹ Òjíṣẹ́ Ọlọhun, Ibnu Jud’aan maa n da ibi pọ ni asiko ki Isilaamu to de, o si maa n fun awọn alaini ni oúnjẹ, njẹ ìyẹn maa ṣe e ni anfaani? O sọ pe: “Ko lee ṣe e ni anfaani, nitori pe ko fi ọjọ kan sọ pé: Irẹ Oluwa mi, fori awọn àṣìṣe mi jin mi ni ọjọ ẹsan".Muslim gba a wa
Lati ọdọ Jaabir – ki Ọlọhun yọnu si i– o sọ pe: Mo gbọ ti Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – n sọ pe: «Dajudaju nkan ti n bẹ laarin ọmọniyan ati mimu orogun mọ Ọlọhun ati ṣiṣe keferi ni gbigbe irun jù silẹ».Muslim gba a wa
عَنْ أَنَسِ بْنِ مَالِكٍ رَضِيَ اللَّهُ عَنْهُ، عَنِ النَّبِيِّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ: "ثَلاَثٌ مَنْ كُنَّ فِيهِ وَجَدَ حَلاَوَةَ الإِيمَانِ: أَنْ يَكُونَ اللَّهُ وَرَسُولُهُ أَحَبَّ إِلَيْهِ مِمَّا سِوَاهُمَا، وَأَنْ يُحِبَّ المَرْءَ لاَ يُحِبُّهُ إِلَّا لِلَّهِ، وَأَنْ يَكْرَهَ أَنْ يَعُودَ فِي الكُفْرِ كَمَا يَكْرَهُ أَنْ يُقْذَفَ فِي النَّارِ".متفق عليه
عَنِ الْعَبَّاسِ بْنِ عَبْدِ الْمُطَّلِبِ رضي الله عنه أَنَّهُ سَمِعَ رَسُولَ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ، يَقُولُ: «ذَاقَ طَعْمَ الْإِيمَانِ مَنْ رَضِيَ بِاللهِ رَبًّا، وَبِالْإِسْلَامِ دِينًا، وَبِمُحَمَّدٍ رَسُولًا».رواه مسلم
عن جابر بن عبد الله قال: كان رسول الله صلى الله عليه وسلم إذا خطب احمرَّتْ عيناه، وعلا صوته، واشتد غضبه، حتى كأنه مُنذِرُ جيشٍ يقول: صبَّحكم ومسَّاكم، ويقول: «بُعثتُ أنا والساعةُ كهاتين»، ويقرن بين إصبعيه السبابة، والوسطى، ويقول: «أما بعد، فإن خير الحديث كتاب الله، وخير الهدى هدى محمد، وشر الأمور محدثاتها، وكل بدعة ضلالة» ثم يقول: «أنا أولى بكل مؤمن من نفسه، من ترك مالًا فلأهله، ومن ترك دينًا أو ضَياعًا فإليَّ وعليَّ».رواه مسلم