Hadith for the World
Àwọn orúkọ ati awọn ìdájọ́

Awọn ipin igbagbọ

3 hadiths

3 hadiths

Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: Ẹ yára si awọn iṣẹ daadaa siwaju ki awọn fitina kan ti yio da bii oru ti o ṣokunkun gan o to de, ti ọmọniyan o ji ni mumini ti yio si di alẹ ni keferi, tabi ki o di alẹ ni mumini ki o si ji ni keferi, ti yio ta ẹsin rẹ tori adun aye ti ko nii pẹ tan.Muslim gba a wa
عن أبي هريرة رضي الله عنه مرفوعاً: «الإيمانُ بِضْعٌ وَسَبْعُونَ أو بِضْعٌ وسِتُّونَ شُعْبَةً: فَأَفْضَلُهَا قَوْلُ: لا إله إلا الله، وَأَدْنَاهَا إِمَاطَةُ الأَذَى عَنِ الطَّرِيقِ، وَالحَيَاءُ شُعْبَةٌ مِنَ الإِيمَانِ».متفق عليه
Lati ọdọ Abu Maalik Al-Ash’ari- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Imọra ni idaji igbagbọ, ati pe sisọ gbolohun ALHAMDULILLAH maa n kun òṣùwọ̀n, ati pe sisọ gbolohun ALHAMDULILLAH ati gbolohun SUBHAANALLAH, mejeeji maa n kun- tabi o n kun- nnkan ti o n bẹ laaarin sanmọ ati ilẹ, ati pe irun jẹ imọlẹ, saara jẹ awijare, suuru jẹ imọlẹ, Kuraani maa jẹ ẹri fun ẹ tabi ki o tako ẹ, gbogbo eniyan yoo maa jáde lọ ní aarọ ni ẹni ti o n ta ẹmi ara rẹ, ninu ki o la a kúrò ninu iná, tabi ki o ko ìparun ba a”.Muslim gba a wa