1 hadiths
Lati ọdọ Abu Hurairah, ki Ọlọhun yọnu si i, o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, sọ pe: «Dajudaju irun ti o wuwo ju fun awọn munaafiki ni irun Ishai ati Asunbaa, ka ni wọn mọ nkan ti n bẹ ninu rẹ - ni ẹsan – ni, wọn o ba wa ki i koda ki o jẹ ni irakoro, ati pe mo ti wa gbero lati paṣẹ ki wọn o gbe irun duro, lẹyin naa ki n wa pa ẹnikan laṣẹ ki o ki i, lẹyin naa ki n wa gbera pẹlu awọn ọkunrin kan ti idi igi wa pẹlu wọn lọ si ọdọ awọn ijọ kan ti wọn o ki n wa ki irun ni masalaasi, ki n si sun ile wọn mọ wọn lori».Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni