Hadith for the World
Irun

Ijẹ dandan irun ati idajọ ẹni ti o ba gbe e ju silẹ

5 hadiths

5 hadiths

Lati ọdọ Amru ọmọ Shu'aib lati ọdọ baba rẹ lati ọdọ baba baba rẹ, o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Ẹ pa awọn ọmọ yin láṣẹ pẹlu irun ti wọn ba ti wa ni ọmọ ọdun meje, ẹ na wọn lori rẹ ti wọn ba ti wa ni ọmọ ọdun mẹwaa, ẹ ṣe opinya laaarin wọn nibi awọn ibusun".Abu Daud ni o gba a wa
Lati ọdọ Buroida ọmọ Al-Husoib- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ẹ tete maa ki irun Asr, dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ẹni ti o ba gbe irun Asr ju silẹ, dajudaju iṣẹ rẹ ti bajẹ”.Bukhaariy gba a wa
Lati ọdọ Abdullāh ọmọ Umar - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Wọn mọ Isilaamu pa lori nkan márùn-ún: Ijẹrii pe ko si ẹni ti ijọsin ododo tọ si ayaafi Allāhu, ati pe dajudaju Muhammad ẹru Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ ni, ati imaa gbe irun duro, ati imaa yọ zakah, ati imaa gbero ile Oluwa, ati gbigba aawẹ Ramadan».Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Lati ọdọ Anas ọmọ Maalik- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: “Ẹni ti o ba gbagbe irun kan ki o yaa ki i nigba ti o ba ranti rẹ, ko si ìpẹ̀ṣẹ̀rẹ́ fun un afi ìyẹn: (Kí o sì kírun fún ìrántí Mi.) (Ta-Ha: 14)”.Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Lati ọdọ Jaabir – ki Ọlọhun yọnu si i– o sọ pe: Mo gbọ ti Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – n sọ pe: «Dajudaju nkan ti n bẹ laarin ọmọniyan ati mimu orogun mọ Ọlọhun ati ṣiṣe keferi ni gbigbe irun jù silẹ».Muslim gba a wa