TopicÀwọn ìwà dáadáa ati awọn ẹkọ
288 hadiths
288 hadiths
Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i-: Lati ọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, ninu nǹkan ti o gba wa lati ọdọ Olúwa rẹ tí Ó lágbára ti O gbọnngbọn, O sọ pe: “Ẹru mi da ẹṣẹ kan, o wa sọ pé: Irẹ Ọlọhun, fi orí ẹṣẹ mi jin mi, Ọlọhun Àlekè-ọla wa sọ pé: Ẹrú Mi da ẹṣẹ kan, o si mọ pe oun ni Olúwa kan ti maa n ṣe àforíjìn ẹṣẹ, ti O si maa n fi iya ẹṣẹ jẹ eeyan, lẹyin naa o tun ṣẹri pada si idi ẹṣẹ, o wa tun sọ pé: Irẹ Oluwa mi, fi ori ẹṣẹ mi jin mi, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga tun sọ pé: Ẹrú Mi da ẹṣẹ kan, o si mọ pe oun ni Olúwa kan ti maa n ṣe àforíjìn ẹṣẹ, ti O si maa n fi iya ẹṣẹ jẹ eeyan, lẹyin naa o tun ṣẹri pada si idi ẹṣẹ, o wa tun sọ pé: Irẹ Oluwa mi, fi ori ẹṣẹ mi jin mi, Ọlọhun ti ọla Rẹ ga tun sọ pé: Ẹrú Mi da ẹṣẹ kan, o si mọ pe oun ni Olúwa kan ti maa n ṣe àforíjìn ẹṣẹ, ti O si maa n fi iya ẹṣẹ jẹ eeyan, maa ṣe ohun ti o ba fẹ́, mo ti fi ori jin ọ”.Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni