Hadith for the World
Tap the image to view it full size
Àwọn ìwà dáadáa ati awọn ẹkọ

Lati ọdọ Thaobān - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe:

Available in 59 languages
«Lati ọdọ Thaobān - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Dinar (owo) ti o lọla julọ ti ọmọniyan n na ni dinar (owo) ti o na fun awọn ara ilé rẹ, ati owo ti o na lori nkan ọ̀gùn rẹ lọ si oju-ọna Ọlọhun, ati owo ti o na lori awọn ẹmẹwa rẹ ni oju-ọna Ọlọhun» Abu Qilābah wa sọ pe: O bẹrẹ pẹlu ara ilé, lẹyin naa ni Abu Qilābah wa sọ pe: Ẹni wo ni ẹsan rẹ fi wa n tobi ju ẹni ti o n na owo lori awọn ọmọ rẹ kéékèèké, ti ko nii jẹ ki wọn maa tọrọ jẹ, tabi ti Ọlọhun o fi i ṣe wọn ni anfaani ti yio si tun rọ wọn lọrọ.»

Meaning translation ·

Explanation

The meaning in a few plain lines

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye oríṣiríṣi ọ̀nà téèyàn lè gbà náwó, ti o si tun to o ti awọn ọna inawo ba fún pọ̀ ni ibamu si bi wọn ṣe jẹ dandan le ọ l'ori si, ni o wa bẹrẹ pẹlu eyiti o pataki julọ lẹyin naa eyiti o pataki tẹle e. Ni o wa sọ pe dajudaju owo ti ẹsan rẹ pọ ju ni eyi ti musulumi na lori awọn ti inawo wọn jẹ dandan fun un; bii iyawo ati ọmọ, Lẹyin naa ni inawo lori nkan ọ̀gùn ti wọn pese kalẹ fun ijagun si oju-ọna Ọlọhun, Lẹyin naa ni inawo lori awọn ọrẹ ati alabaarin ni igba ti wọn n jagun si oju-ọna Ọlọhun.

Source
Muslim gba a wa
Download image

Saved at original quality