Hadith for the World
Tap the image to view it full size
Àwọn ìwà dáadáa ati awọn ẹkọ

Lati ọdọ Abu Hurairah - ki Ọlọhun yọnu si i - ó ṣo pé: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe:

Available in 71 languages
«Lati ọdọ Abu Hurairah - ki Ọlọhun yọnu si i - ó ṣo pé: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: “Ẹ má ṣe sọ ilé yín di saare, ẹ sì má sọ saare mi di àáye àjọ̀dún, ẹ maa ṣe asalatu fún mi; dajudaju asalatu yín ó kàn mi lara lati ibikibi ti ẹ ba wa.»

Meaning translation ·

Explanation

The meaning in a few plain lines

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n kọ̀ fún wa níbi kí a má maa ki ìrun ninu awọn ile wa, tí awọn ile naa yio waa da gẹgẹ bii itẹ́ awọn òkú, tí ẹnikẹni kò gbọdọ̀ kirun nibẹ. O sì kọ̀ fun wa lati maa ṣe àbẹ̀wò saare rẹ̀ léraléra ati imaa kójọ sibẹ ni igba gbogbo; nitori pe iyẹn jẹ́ ọna kan tí ó lè mu wa wọ inu ẹbọ. Ó paṣẹ pe ki a maa tọrọ ìkẹ́ ati ìgẹ̀ fun oun ni ibikibi lori ilẹ aye; nitori pe iyẹn yoo kàn án lara lati ọdọ ẹniti ó sunmọ ati ẹniti ó jinna bakan naa, nitori naa a o ni bukata si ki a maa paara ibi saare rẹ̀.

Source
Abu Daud ni o gba a wa
Download image

Saved at original quality