19 hadiths
Lati ọdọ Abu Musa Al-ash’ari - ki Ọlọhun yọnu si i - ó sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pé: “Àpèjúwe Mumini ti n ka Kuraani da gẹgẹ bii èso utrujjah, ti oorun rẹ daa, ti itọwo rẹ naa si daa, àpèjúwe mumini ti kii ka Kuraani da gẹgẹ bii èso dabinu, ti ko ni oorun, ti itọwo rẹ si dùn, àpèjúwe munaafiki ti n ka Kuraani da gẹgẹ bii èso rayhaanah, ti oorun rẹ dùn, ti itọwo rẹ si korò, àpèjúwe munaafiki ti kii ka Kuraani da gẹgẹ bii èso hansọla, ti ko ni oorun, ti itọwo rẹ tún korò".Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Lati ọdọ Ubay ọmọ Kahb- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Irẹ Abu Al-Munzir, ǹjẹ́ o mọ aaya wo ninu tira Ọlọhun ti o wa pẹlu rẹ ni o tobi julọ?”, o sọ pe: Mo sọ pé: Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ ni wọn ni imọ julọ. O sọ pe: “Irẹ Abu Al-Munzir, ǹjẹ́ o mọ aaya wo ninu tira Ọlọhun ti o wa pẹlu rẹ ni o tobi julọ?”, o sọ pe: Mo sọ pé: {Allāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun, Alààyè, Alámòjúútó-ẹ̀dá} [Al-Baqarah: 255]. O sọ pe: O wa fi ọwọ́ lu mi láyà, o wa sọ pé: “Mo fi Ọlọhun búra, o kú oriire imọ naa, ki Ọlọhun ṣe e ni irọrun fun ẹ, irẹ Abu Al-Mundhir”.Muslim gba a wa