135 hadiths
Lati ọdọ Abu Maalik Al-Ash’ari- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Imọra ni idaji igbagbọ, ati pe sisọ gbolohun ALHAMDULILLAH maa n kun òṣùwọ̀n, ati pe sisọ gbolohun ALHAMDULILLAH ati gbolohun SUBHAANALLAH, mejeeji maa n kun- tabi o n kun- nnkan ti o n bẹ laaarin sanmọ ati ilẹ, ati pe irun jẹ imọlẹ, saara jẹ awijare, suuru jẹ imọlẹ, Kuraani maa jẹ ẹri fun ẹ tabi ki o tako ẹ, gbogbo eniyan yoo maa jáde lọ ní aarọ ni ẹni ti o n ta ẹmi ara rẹ, ninu ki o la a kúrò ninu iná, tabi ki o ko ìparun ba a”.Muslim gba a wa
Lati ọdọ Mu’aadh- ki Ọlọhun yọnu si i-, o sọ pe: Mo wa lẹyin Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lori kẹtẹkẹtẹ kan ti wọn n pe ni ‘Ufair, o sọ pe: “Irẹ Mu’aadh, njẹ o mọ iwọ Ọlọhun lori awọn ẹrusin Rẹ, ati nnkan ti o jẹ iwọ àwọn ẹrusin lori Ọlọhun?”, mo sọ pe: Ọlọhun ati Ojiṣẹ Rẹ ni wọn ni imọ julọ, o sọ pe: “Dajudaju iwọ Ọlọhun lori awọn ẹrusin ni ki wọn maa jọsin fun Un ki wọn si ma da nnkan pọ mọ Ọn ninu ẹbọ, iwọ àwọn ẹrusin lori Ọlọhun ni ki O ma fi iya jẹ ẹni ti ko ba da nnkan pọ mọ Ọn ninu ẹbọ”, mo sọ pe: Irẹ Òjíṣẹ́ Ọlọhun, ṣe ki n maa fun awọn eniyan ni iro idunnu nipa rẹ? O sọ pe: “Rara, ma fun wọn ni iro ìdùnnú, ki wọn ma baa gbára lé e”.Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i-: Dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: “Ọjọ igbende ko lee to titi orun fi maa yọ lati ibuwọ rẹ, ti o ba ti yọ ti awọn eniyan ti wa ri i, gbogbo wọn maa gbagbọ lapapọ, ìyẹn ni igba ti: (ìgbàgbọ́ (tí) ẹ̀mí kan kò tí ì gbàgbọ́ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ tàbí iṣẹ́ rere (tí) ẹ̀mí kan kò tí ì fi ìgbàgbọ́ rẹ̀ ṣe (tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀) kò níí ṣe é ní àǹfààní (lásìkò náà)) Al-An’am, Ayah 158. Alukiyaamọ maa tó, ti ọkùnrin meji si ti tẹ aṣọ silẹ láàrin ara wọn, wọn ko si nii lee ta ọjà fun ara wọn bẹẹ ni wo ko si nii lee ka a padà, alukiyaamọ maa tó, ti èèyàn si ti bu wàrà ràkúnmí rẹ lọ ti ko si nii le mu u, alukiyaamọ maa tó, ti ó sì ti tún àmù omi rẹ ṣe, ko si nii le fun awọn ẹran ọ̀sìn rẹ mu nínú ẹ, alukiyaamọ maa tó, ti ẹnìkan nínú yin si ti gbe oúnjẹ rẹ sí ẹnu, ko si nii lee jẹ ẹ”.Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni