Hadith for the World
Hajj ati Umrah

‏Ọla ti n bẹ fun hajj ati Umrah

5 hadiths

5 hadiths

Lati ọdọ ọmọ Abbās - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ fun arabinrin kan ninu awọn Ansaar, Ibnu Abbās darukọ rẹ, mo wa gbagbe orukọ rẹ, o sọ fun un pe: «Kini o kọ fun ọ lati ṣe hajj pẹlu wa?» O sọ pe: A ko ni ju rakunmi meji lọ (ti a fi maa n fun oko wa lomi) ti ọkọ rẹ ati ọmọ rẹ si ṣe irinajo hajj lori ẹyọkan, o si fi ẹyọkan silẹ fun wa lati maa lo o lati fi maa pọn omi, o sọ pe: «Ti Ramadan ba ti de ki o yaa ṣe umurah; tori pe dajudaju umurah inu rẹ ṣe deedee hajj».Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Lati ọdọ Abu Hurairah, ki Ọlọhun yọnu si i, o sọ pe: Mo gbọ Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, ti n sọ pe: "Ẹnikẹni ti o ba ṣe Hajj nitori ti Ọlọhun, tí kò ba obinrin lopọ, tí kò sì rú ofin Ọlọhun, onitọhun yoo pada sile gẹgẹ bi ọjọ ti iya rẹ̀ bi i."Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Lati ọdọ Āisha iya àwọn mumini - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, a n ri pe jihad (ijagun si oju-ọna Ọlọhun) ni iṣẹ ti o lọla julọ, ṣe aa nii jagun ni? O sọ pe: «Rara, ṣugbọn jihad (ijagun si oju-ọna Ọlọhun) ti o lọla julọ ni: hajj ti o mọ kanga (ti o jẹ atẹwọgba)».Bukhaariy gba a wa
عن عائشة رضي الله عنها مرفوعاً: «ما مِن يومٍ أكثر مِن أنْ يُعْتِقَ اللهُ فيه عبدًا مِن النارِ، مِن يومِ عرفة، وإنَّه ليدنو، ثم يُباهي بهم الملائكةَ، فيقول: ما أراد هؤلاء؟».رواه مسلم
عن أبي هريرة رضي الله عنه: أن رسول الله صلى الله عليه وسلم قال: «العمرة إلى العمرة كفارةٌ لما بينهما، والحج المبرور ليس له جزاءٌ إلا الجنة».متفق عليه