Hadith for the World
Tap the image to view it full size
Fik'hu ati ìpìlẹ̀ rẹ

Lati ọdọ ọmọ Abbās - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji - o sọ pe:

Available in 60 languages
«Lati ọdọ ọmọ Abbās - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ fun arabinrin kan ninu awọn Ansaar, Ibnu Abbās darukọ rẹ, mo wa gbagbe orukọ rẹ, o sọ fun un pe: «Kini o kọ fun ọ lati ṣe hajj pẹlu wa?» O sọ pe: A ko ni ju rakunmi meji lọ (ti a fi maa n fun oko wa lomi) ti ọkọ rẹ ati ọmọ rẹ si ṣe irinajo hajj lori ẹyọkan, o si fi ẹyọkan silẹ fun wa lati maa lo o lati fi maa pọn omi, o sọ pe: «Ti Ramadan ba ti de ki o yaa ṣe umurah; tori pe dajudaju umurah inu rẹ ṣe deedee hajj».»

Meaning translation ·

Explanation

The meaning in a few plain lines

Nígbà tí Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣẹri lati hajj idagbere, o sọ fún arabinrin kan ninu Ansaar ti ko ṣe hajj pe: Kini nkan ti o kọ fun ọ lati ṣe hajj pẹlu wa? O wa mu awijare wa pe awọn ni rakunmi meji, ti ọkọ oun ati ọmọ òun si ṣe hajj lori ọkan ninu mejeeji, ti o si fi ẹyọkan silẹ lati lẹ maa fi i pọn omi lati inu kanga. Ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa fun un ni iro pe dajudaju ṣiṣe umurah ninu oṣu ramadan ẹsan rẹ ṣe deedee ẹsan hajj.

Source
Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni
Download image

Saved at original quality