TopicÀwọn ìwà dáadáa ati awọn ẹkọ
288 hadiths
288 hadiths
Lati ọdọ Shaddad bin Aws, ki Ọlọhun yọnu si i, lati ọdọ anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a –: “Olori iwaforijin ni ki o sọ pe: Allahummọ anta Rọbbii laa ilaaha illaa anta, khalaqtanii, wa anaa abduka wa anaa alaa ahdika wawahdika mastatahtu, auuzu bika min sharri maa sanahtu, abuuhu laka binihmatika alayya, wa abuuhu bizambii, fagfir lii, fa innahuu laa yagfiruz zunuuba illaa anta", o sọ pe: Ẹni ti o ba sọ ọ ni aarọ ti o si ni amọdaju pẹlu ẹ, ti o wa kú, ni ọjọ naa ki o to di irọlẹ, o maa wa ninu awọn ọmọ alujanna, ẹni tí ó bá sọ ọ ni alẹ ti o si ni amọdaju pẹ̀lú ẹ, ti o wa kú ki ilẹ o to mọ́, o maa wa ninu awọn ọmọ alujanna".Bukhaariy gba a wa